Stephen Ajagbe, Ilọrin
Nitori bi atankalẹ arun Koronafairọọsi ṣe n fojoojumọ gbilẹ nipinlẹ Kwara, ijọba ti ṣekilọ pe, bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ta a wa yii, ẹnikẹni, bo ti wu ko ri, tọwọ ba tẹ ti ko lo ibomu yoo da ara rẹ lẹbi.
Bakan naa, gbogbo awọn to ni ile itaja, awọn awakọ atawọn oniṣọọbu to ba gba awọn ti ko lo ibomu laaye lati wọle, ijọba yoo fi pampẹ ọba gbe iru wọn naa, wọn yoo si jẹ iya to ba tọ si ẹni to tapa sofin.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin gomina to tun jẹ Alukoro fun igbimọ to n gbogun ti arun Covid-19 nipinlẹ Kwara, Rafiu Ajakaye, fi sita lo ti sọ pe bi arun naa ṣe n tan kiri kọ ijọba lominu gidi.
O ni gbogbo araalu patapata; atawọn oniṣọọbu itaja, awọn awakọ ero ati ayọkẹlẹ, pẹlu awọn to n rin kaakiri igboro ni ofin bibo imu de o, ẹni to ba si tapa si i, kele yoo gbe e, yoo si foju bale-ẹjọ.
O ni ijọba ko ni i laju silẹ lati maa wo awọn kọlọransi ẹda kan ki wọn maa ṣe ohun to le ṣe akoba fun eto ilera araalu, idi niyi tawọn fi fẹẹ fọwọ lile mu awọn eeyan.
Ofin tuntun ọhun waa ṣalaye yekeyeke pe, ẹni ti ko ba lo ibomu ko ni i le raaye wọle si ọọfiisi tabi ileeṣẹ kankan, ọja, awọn ile itaja nla, inu ọkọ ero, ilefowopamọ ati bẹẹ lọ.
O nijọba yoo tu awọn ikọ kan jade bẹrẹ lati ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu keje, ọdun yii. Ẹni ti wọn ba gba mu, lẹyin ti wọn ba foju ẹ bale-ẹjọ alaagbeka tan, wọn yoo tun ru u lọ sibudo iyasọtọ.
Ijọba waa ni gbogbo awọn ile iworan bọọlu, awọn ibudo igbafẹ ati ayẹyẹ to ba gba awọn eeyan to ju mẹẹẹdọgbọn laaye yoo di titi.
Eeyan mẹtadinlaaadọrun lo tun ko arun Korona lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii ni Kwara.