Gomina ipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi ti ko arun Koronafairọọsi o

Gomina Kayọde Fayẹmi tipinlẹ Ekiti ti ko arun Koronafairọọsi.

Gomina ọhun funra ẹ lo ṣe ikede lori ikanni Twitter laaarọ yii.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni oun ṣe ayẹwo kẹta, esi si jade lanaa. O waa ni oun ko ṣaisan, koko lara oun le, oun si wa nile lati gba itọju gidi.

Bakan naa lo ni oun ti gbe awọn aṣẹ kan le igbakeji oun, Ọtunba Bisi Ẹgbẹyẹmi, lọwọ lati maa ba ijọba lọ.

Leave a Reply