Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Owuyẹ, aṣoroosọ bii ọrọ lọrọ da fun ọmọkunrin ẹni ọdun mejidinlọgbọn kan, Kehinde Adesọgba Adekusibẹ, ẹni tawọn ọlọpaa ti mu bayii pe o sọrọ to ta ko ofin to de agbejade ọrọ lori ikanni ayelujara.
Ọjọ kejidinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii ni Kẹhinde bọ sori ikanni tuita, to si n sọ pe, “Ẹ jẹ ka pa gbogbo awọn ẹya Ibo danu. Ẹ jẹ ka palẹ wọn mọ kuro nilẹ Yoruba. Mo koriira awọn eeyan yii tọkantọkan. Onijagidijagan ni wọn. Wọn buru pupọ. Wọn korira wa. Ẹ jẹ ki awa naa koriira wọn lai da ẹnikẹni si”.
Latigba to ti sọrọ yii, gẹgẹ bi Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, ti wi, ni ẹka to n gbogun ti iwakiwa lori ẹrọ ayelujara ti bẹrẹ iwadii, ko si pẹ ti wọn fi ri Kẹhinde mu niluu Ileṣa, nibi to sa pamọ si.
Ọpalọla ni ọmọnkunrin naa ti jẹwọ, yoo si foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba pari lori ẹsun ti wọn fi kan an.