Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ọga ọlọpaa patapata lorilẹ-ede yii, Mohammed Adamu, ṣabẹwo solu ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Eleweeran, l’Abẹokuta, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 2020, nibi to ti gbà awọn ọlọpaa nimọran lati maa ṣiṣẹ wọn lọna to yẹ.
Ọkọ baaluu agberapaa to gbe Adamu wa lati Abuja si Eleweeran, balẹ ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ kọja iṣẹju diẹ, awọn ọga lẹnu iṣẹ ọlọpaa bii AIG Ahmed Iliyasu, Igbakeji ọga agba lẹkun ilẹ Yoruba; Lẹyẹ Oyebade ati Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Edward Ajogun, pẹlu àwọn ọga mi-in lo gba ọga agba pata naa lalejo l’Eleweeran.
Nigba to n ba awọn ọlọpaa sọrọ, IGP Adamu gba wọn niyanju lati jẹ akinkanju lẹnu iṣẹ wọn. O ni ki wọn duro ṣinṣin lori otitọ, ki wọn si maa ṣiṣẹ wọn ni ibamu pẹlu ofin iṣẹ ọlọpaa.
Bi wọn ba n ṣe eyi, ọga agba ni ki i ṣe pe wọn yoo jẹ anfaani gbogbo to tọ si wọn lẹnu iṣẹ nikan kọ, o ni bi wọn ba fẹyinti paapaa, wọn yoo maa jere iṣẹ ti wọn ṣe silẹ lọ ni.
Awọn anfaani eto ilera labẹ ma-da-n-dofo (Health insurance) atawọn mi-in lọga agba sọ pe yoo to ọlọpaa to ba ṣiṣẹ rẹ deede lọwọ, bẹẹ lo rọ wọn lati ma ṣe kaaarẹ ọkan pẹlu ipenija to koju wọn kọja. O ni ki wọn ma tori iṣẹlẹ to gba ẹmi awọn kan ninu wọn ṣojo.