Jọkẹ Amọri
Niṣe ni gbogbo ilu Ogbomọsọ dakẹ rọrọ, ti awọn araalu to ti gbọ nipa iku Ṣoun Ogbomọsọ, Ọba Ọladunni Oyewumi, Ajagungbade Kẹta, si n daro iku gbajumọ ọba naa.
Awọn ti wọn fi iroyin naa to ALAROYE leti ṣalaye pe lọwọ alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu kejila, ọdun yii, ni Ọba Ọladuni to ti lo ọdun mẹtadinlaaadọta lori oye waja.
Bo tilẹ jẹ pe okiki iku ọba naa ko ti i kan kaakiri ilu, awọn afọbajẹ atawọn tọrọ kan ti n mura ati tufọ ilu Ọba Ọladunni.
Ẹni ọdun marundinlọgọrun-un ni Kabiyesi ko too darapọ mọ awọn baba nla rẹ. Oniṣowo pataki ni, ilu Jos lo gbe to ti n ṣe ka-ta-ka-ra ko too di pe o pada wa siluu Ogbomọṣọ lati waa jọba.
ALAROYE yoo maa fi to yin leti bo ba ṣe n lọ.