Jọkẹ Amọri
Ọga agba ninu awọn oṣere, to si tun dagba ju lọ ninu awọn onitaita lasiko to wa laye, Charles Olumọ Sanyaolu, ti gbogbo eeyan mọ si Agbako ti ku o.
L’Ọjọruu, Tọsidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, ni baba naa mi eemi ikẹyin, to si ki aye pe o digbooṣe lẹni ọdun mọkanlelọgọrun-un.
Adari ẹgbẹ awọn oṣere, Bọlaji Amusan, lo kede ipapoda baba naa lori ayelujara, nibi to kọ ọ si pe, ‘tampanglobal kede iku Pa Charles Olumọ Sanyaolu ti gbogbo eeyan mọ si Agbako. A oo maa kede bi eto isinku rẹ ba ṣẹ n lọ fun yin’’.
ALAROYE gbọ pe laaarọ kutu ọjọ Tọsidee ni baba yii dagbere faye. Awọn to sun mọ mọlẹbi oloogbe naa sọ pe baba naa kan sọ pe o rẹ oun diẹ ni, ki ọloju si too ṣẹ ẹ peu, ẹlẹmi-in ti gba a.
Lasiko ti baba yii pe ọgọrun-un ọdun ni awọn eeyan ṣayẹyẹ nla fun un. Bi awọn oṣere ṣẹ ṣe fun un, bẹẹ ni awọn eeyan mi-in paapaa ti wọn mọ riri ipa ti baba naa ti ko ninu ere tiata ṣe fun un. Lara wọn ni wolii ariran nni, Primate Ayọdele, ẹni to fun baba yii lẹbun owo, to si fi i si ori owo oṣu ti yoo maa fi tọju ara ẹ. Ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un Naira ni wolii naa ṣeleri lati maa fun baba yii titi ti yoo fi jade laye.
Ere ‘’Ogboju Ọdẹ ninu Igbo Irunmọlẹ’’ ti Fagunwa ṣe, ṣugbọn ti wọn pada fi ṣe ere, nibi ti baba naa ti kopa ọkan ninu awọn akanda ẹda ti awọn to n lọ si Igbo irunmọlẹ ba pade, eyi ti wọn pe ni agbako lo gbe Olumọ jade. Ọpọ ni ko si mọ orukọ abisọ rẹ gan-an, orukọ ipa to ko ninu ere yii ni ọpọlọpọ fi maa n pe e.
Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 1923, ni wọn bi Charles Sanyaolu ti wọn pe ni Agbako yii.
Ileewe alakọọbẹrẹ lo ti bẹrẹ ere tiata gẹgẹ bo ṣẹ sọ nigba to wa laye. Lẹyin naa lo lọ sileewe girama, to si tun kọṣẹ mẹkaniiki. Ṣugbọn nigba ti okiki de lo pa iṣẹ ọwọ to kọ ti, to si gbaju mọ iṣẹ tiata to ṣe titi ti ọlọjọ fi de. Bo tilẹ jẹ pe Musulumi ni Baba Sanyaolu, ile ijọsin lo sọ pe oun ti bẹrẹ ere ori itage. Lasiko igba naa, o maa n tẹle awọn oṣere lọ sibi ti wọn ti maa n palẹmọ fun ere ni, kẹrẹkẹrẹ loun naa darapọ mọ wọn nitori ifẹ to ni si iṣẹ naa.
Baba yii maa n ja ẹsẹ nigba to wa ni Ṣango-ode, eyi lo fi jẹ pe pẹlu pe baba naa ti dagba, o maa n rin jade, to si tun maa n ṣe ọpọlọpọ nnkan ti awọn ti wọn jọ jẹ sawawu lọjọ ori ko le ṣe. Ọmọ bibi ilu Abẹokuta, nipinlẹ Ogun, ni Baba Agbako.
Bo tilẹ jẹ pe Charles Olumọ Ṣanyaolu ni wọn tẹ mọ ọn lara, orukọ abisọ rẹ gan-an ni Iṣọla Abdusalam Sanyaolu. Ileejọsin to ti n ba wọn ṣere ni wọn ti fun un ni orukọ Charles to n jẹ. Orukọ to sọ ẹgbẹ ere ori itage rẹ, iyẹn Olumọ, ni awọn eeyan so papọ ti wọn fi n pe e ni Charles Olumọ.
Nigba ti baba naa ṣi wa ni abarapaa, wọn ko ri i ajọ ko kun ni ninu ere tiata. Ko si ere agbelewo tabi ti ori itage ti yoo jade nigba naa ti ko ni i kopa nibẹ. O si ṣọro lati sọ pe iye fiimu bayii ni ọkunrin naa ti kopa.
Lara awọn ere ti agba ọjẹ ninu ere tiata yii kọ funra rẹ ni, ‘’Ajanaku’’ ‘’Agba Aja’’ ati ‘’Ajana Oro’’
Ẹni ọdun mọkanlelọgọrun-un ni baba naa ko too dagbere faye.