Esi idibo aarẹ yii ko tẹ awọn ọmọ Naijiria lọrun o, ki INEC ṣatunṣe lori ẹ – Amẹrika

Monisọla Saka

 Aṣoju orilẹ-ede Amẹrika lorilẹ-ede Naijiria, Mary Beth Leonard, ti sọ pe ibo aarẹ ọdun 2023 to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ko jẹ itẹwọgba fawọn ọmọ Naijiria, ko si tẹ wọn lọrun rara, tori ko lọ bo ṣe yẹ ko lọ.

Obinrin yii ni ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria ni inu n bi latari esi idibo ọhun, nigba tawọn mi-in si n fo f’ayọ, pẹlu bi wọn ṣe ro pe oriire ọhun tọ sawọn, nitori awọn ṣiṣẹ takuntakun ko too tẹ awọn lọwọ. O waa gboriyin fawọn ọmọ Naijiria fun bi wọn ṣe dide lati ṣiṣẹ tọ ijọba awa-ara-wa lẹyin.

Nidii eyi, Leonard rọ ajọ eleto idibo ilẹ yii, INEC, lati tete wa ojutuu si ọrọ naa ko too di ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ti ibo gomina yoo waye, ki wọn ma si ṣe gbagbe lati wo nnkan to ṣokunfa awọn kudiẹ-kudiẹ to waye lasiko ibo aarẹ, ki wọn le wa ọna abayọ si i, kiru ẹ ma baa tun ṣẹlẹ lasiko ibo gomina ati lọjọ iwaju.

Bẹẹ lo tun fi kun un pe, kawọn ajọ INEC maa bun awọn ọmọ Naijiria, atawọn oniroyin gbọ, nipa oniruuru igbesẹ ti wọn ba n gbe lori ọrọ naa.

Bakan naa ni Leonard tun gboṣuba ‘o kare’ fun oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Peter Obi ati Atiku Abubakar, ti i ṣe oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), fun ifọmọniyan-ṣe ati akitiyan wọn lati gba ile-ẹjọ lọ, ki wọn le yanju aawọ ti esi idibo aarẹ da kalẹ, ati aarẹ tuntun ti ajọ INEC ṣẹṣẹ kede, Aṣiwaju Bọla Tinubu, fun bo ṣe fara mọ erongba awọn alatako ẹ lati ṣe bẹẹ.

Apa kan atẹjade naa ka bayii pe, “Awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bi ijọba awa-ara-wa ṣe pe fun, lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, ṣugbọn ọpọlọpọ ni inu n bi, ti ara si n kan, nigba tawọn mi-in ninu wọn gba ilu, ti wọn n ṣe ajọyọ, nitori wọn gbagbọ pe oriire ijawe olubori tawọn jiṣẹ-jiya fun, to tọ si awọn ni.

Pẹlu bọrọ ṣe n lọ yii, o ṣe pataki fọjọ-iwaju orilẹ-ede yii kawọn ọmọ Naijiria ma ṣe jẹ ki ọrọ yii da iyapa si wọn laarin, ki wọn si faaye gba idajọ kootu ti wọn fẹẹ lo lati yanju ẹ”.

Leonard sọrọ siwaju si i pe gẹgẹ bo ṣe le ma tẹ ọpọlọpọ lọrun lati pari ọrọ ẹjọ ibo yii ni kootu, ninu ofin ijọba awa-ara-wa, ibi ti ọrọ ija to waye latara ọrọ ibo ti le niyanju wa, adajọ naa ni yoo si yanju rẹ. O ni o ti waa han gbangba bayii pe, ayipada ti n de ba ọrọ eto idibo ilẹ Naijiria.

“Fun igba akọkọ, awọn oludije dupo aarẹ mẹrin rọwọ mu ni o kere tan, ipinlẹ kọọkan, awọn mẹta ti wọn n lewaju ninu wọn si wọle nipinlẹ mejila mejila, gẹgẹ bi esi idibo to jade ṣe sọ.

Ninu ibo awọn aṣofin agba naa, koda pẹlu bo ṣe jẹ pe esi idibo wọn ko ti i jade tan, a ti mọbi ti yoo fẹnu sọ, awọn gomina meje ni wọn padanu ninu ibo lati wọle sipo aṣofin, ko din ni awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party meje ti wọn ti rọna wọle sile igbimọ aṣofin, tawọn ọmọ ẹgbẹ NNPP si ri mọkanla mu nile igbimọ aṣoju-ṣofin”.

O waa fawọn ọmọ Naijiria lọkan balẹ pe pẹlu bi ọrọ yii ṣe n lọ, titi kan ti ọsẹ to n bọ, titi ti eto idibo yoo fi kasẹ nilẹ, o lorileede Amẹrika wa pẹlu wa gbagbaagba.

Leave a Reply