Esther Agbaje, ọmọ Naijiria, wọle sipo aṣofin l’Amẹrika

Aderohunmu Kazeem

Ninu ibo to waye nilẹ Amẹrika, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, esi rẹ ti berẹ si i jade diẹdiẹ, awọn eeyan ko si le pa idunnu wọn mọra nigba ti wọn gbọ pe  ọmọ orilẹ-ede Naijiria, to yun jẹ ọmọ Yoruba, Esther Agbaje, toun naa kopa ninu ẹ ti wọle gẹgẹ bii ọmọ ileegbimọ aṣoju-ṣofin Amẹrika ninu ẹgbẹ Democrat.

Ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun mẹtadinlogun (17,396) lo fi di aṣoju-ṣofin, nilẹ Amẹrika, eyi to fun un lanfaani lati ni ibo to le ni ida aadọrin ninu gbogbo ibo ti wọn di ọhun.

Ẹni ti obinrin ọmọ Naijiria yii fidi ẹ janlẹ ninu ibo ọhun ni Alan Shilepsky, ẹni to dije dupo labẹ asia ẹgbẹ oṣelu The Republican Party, ibo to le diẹ ni ẹgbẹrun mẹrin pere (4,126) loun ni.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni District 59B, ni ọmọ Yoruba yii yoo maa ṣoju fun laarin awọn ọmọ ile-igbimọ aṣọju-sọfin mẹrinlelaadoje (134).

ALAROYE gbọ pe ko si iye igba ti eeyan ko le dije fun ipo ọhun.

Agbegbe kan ti wọn n pe ni St. Paul, ni wọn bi ọmọbinrin yii si, ni Minnesota. Ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Refurendi V. John, ni baba ẹ, nigba ti oruko iya rẹ n jẹ Bunmi, oṣiṣẹ yara ikowee-pamọ si ni Yunifasiti Minnesota lawọn mejeeji, ibẹ ni wọn ti pade nigba ti wọn n kẹkọọ lọwọ ki wọn too segbeyawo.

George Washington University, Washington D.C., ni wọn sọ pe Agbaje naa ti kawe gboye imọ ijinlẹ ninu eto oṣelu.

Ọmọ ẹgbẹ oṣelu Democratic-Farmer-Labour Party ni Agbaje n ṣe, bẹẹ ni ẹgbẹ oṣelu naa si ni i ṣe pelu ẹgbẹ oṣelu The Democratic Party  tawọn Joe Biden to n ba Aarẹ ilẹ America, Donald Trump wọ ọ ninu ibo ọhun.

 

Leave a Reply