Ọwọ tẹ Abednego ati ọrẹ ẹ ti wọn n fi ọkada jale l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.

Ajọ Sifu Difẹnsi ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọlọkada kan, Azukwo Abednego, ati ọrẹ rẹ, Ajiwẹ Oluwaṣeun, ti wọn n fi ọkada ja awọn eeyan lole laarin ilu Akurẹ.

Ọga agba fun ajọ naa nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Emeka Edenabu, lo ṣafihan wọn fawọn oniroyin ni olu ileesẹ wọn to wa ni Alagbaka, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. O lo pẹ ti awọn ti n wa awọn ọdaran mejeeji kọwọ too tẹ wọn nibẹrẹ ọsẹ ta a wa yii.

ALAROYE gbọ pe awọn eeyan bii meje ni wọn ti waa fẹjọ awọn ọlọkada naa sun lọfiisi awọn Sifu Difẹnsi lori ọkan-o-jọkan iwa ọdaran ti wọn n hu lawọn agbegbe bii, Ọshinlẹ, Ijọka, Danjuma, Oluwatuyi ati Oke-Aro.

O ni ṣe lọkan ninu awọn afurasi ọhun maa n dibọn bii ọlọkada, ti yoo si fọgbọn tan ero to ba gbe lọ si kọrọ kan, nibi tawọn yooku rẹ sapamọ si, nibẹ ni wọn yoo ti fipa gba gbogbo owo, foonu ati ẹru mi-in to ba wa lọwọ onitọhun.

Awọn nnkan ti wọn ri gba pada lọwọ awọn mejeeji ni, ọkada tuntun ti ko ti i ni nọmba, baagi obinrin ti ọpọlọpọ aṣọ, bata, owó ati foonu mẹta wa ninu rẹ.

Diẹ ninu awọn ti wọn ti ja lole la gbọ pe wọn ti n yọju si ọfiisi ajọ yii, ti  wọn si n jẹrii si i pe ogbologboo adigunjale ni wọn.

Ọgbẹni Emeka ni iwadii ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan wọn, o ni laipẹ lawọn mejeeji yoo foju bale-ẹjọ fun ẹsun idigunjale, jibiti lilu ati idunkooko mọ awọn alaiṣẹ.

Leave a Reply