Faith Adebọla, Eko
Loootọ ni wọn maa n sọ pe ọmọ ẹni ku ya ju ọmọ ẹni sọnu lọ, sibẹ, ibanujẹ nla to ba awọn mọlẹbi ọkunrun ẹni ogoji ọdun kan, Wale Kalejaiye, lasiko yii kọja afẹnusọ, pẹlu bo ṣe jẹ inu alagbalugbu omi okun ni wọn ti lọọ ri oku ẹ lẹyin ọjọ kẹfa to ti wa lakata awọn ẹruuku afurasi ọdaran lagbegbe Lẹkki, nipinlẹ Eko.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, inu ibẹru ati aibalẹ ọkan lawọn eeyan agbegbe Ibẹju-Lẹkki tiṣẹlẹ ọhun ti waye, wa, latọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii, irọlẹ ọjọ Abamẹta, Satide yii, ni wọn ni awọn kan ri oku ọkunrin naa.
Wọn ni lọjọ Aje tiṣẹlẹ ijinigbe naa waye, funra oloogbe yii lo lọọ sọ awọn ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe Lẹkki, bawọn janduku ko ṣe jẹ ki wọn rimu mi, tawọn ole atawọn ẹlẹgbẹ okunkun n yọ wọn lẹnu, n lọkunrin naa ba kegbajare lọ si teṣan ọlọpaa to wa ni Akodo, ni Lẹkki, pe ki wọn ma wo awọn niran.
Awọn ọlọpaa bi i leere pe ṣe o le mu awọn de ọdọ awọn afurasi ọdaran to mọ, o si gba lati ṣe bẹẹ, n lawọn ọlọpaa diẹ lati ikọ IGP Monitoring Unit, atawọn ọlọpaa Moba (Police Mobile Force) ba tẹle e, wọn si mu awọn janduku diẹ lagbegbe ọhun.
Wọn ni iwaju ile baalẹ abule Akodo naa ni wọn ṣi wa, ti baalẹ n ba awọn ọlọpaa sọrọ lọwọ, bawọn janduku kan ti wọn to bii aadọjọ ṣe ya bo wọn nibẹ niyẹn, wọn fẹẹ tu awọn ẹlẹgbẹ wọn ti wọn mu silẹ.
Igba ti eruku rogbodiyan naa yoo fi relẹ, Wale Kalejaiye ti wọn loun lo ṣe alami awọn fawọn agbofinro ti dawati, ko si sẹni to gbọ ‘mo ko o’ rẹ titi ti wọn fi ri oku rẹ yii, wọn ti pa a.
Mọlẹbi oloogbe naa, Jalailu Alimi, ba Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), sọrọ, o ni, ”O buru gidi pe awọn eeyan keeyan yii pa ẹgbọn mi danu lasan. Mi o ri iru iwa ika bii eyi ri laye mi. Awọn janduku yii ti waa di ẹrujẹjẹ laduugbo wa, bo ṣe wu wọn ni wọn n kọ lu awọn ọlọpaa atawọn agbofinro mi-in.
”Owurọ ọjọ Aiku, Sannde, yii lawọn ọlọpaa pe wa lori aago pe awọn ti ri oku ẹgbọn mi gba pada, wọn ni etikun Magbọn, labule Ṣẹgun, lawọn to pa a sọ oku ẹ si. O ba ni ninu jẹ gidi, Ọlọrun lo mọ ohun ti wọn ti foju ẹ ri ko too ja siku yii.”
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Olumuyiwa Adejọbi, naa fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, bo tilẹ jẹ pe o loun ko le sọ pupọ nipa ẹ lasiko yii tori iṣẹ iwadii to lọọrin ṣi n lọ lọwọ.