Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Bọjẹẹti to din diẹ ni biliọnu lọna aadoje naira (#129.7b) ni Gomina Adegboyega Oyetọla gbe aba rẹ fun ti eto iṣuna ọdun 2022 lọ sile-igbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun.
Ninu aba eto-iṣuna naa ni gomina ti sọ pe eto-ẹkọ nijọba oun yoo na owo to pọ ju le lori, nigba ti idagbasoke awọn nnkan amayedẹrun, eto ilera ati eto ọgbin yoo tẹle e.
Aba eto-iṣuna ọhun, eleyii to fi biliọnu lọna ogun naira ju iye tijọba na lọdun 2021 lọ, ni wọn pe ni bọjẹẹti ti yoo tubọ mu ki idagbasoke ba ipinlẹ Ọṣun (Budget of Sustainable Development).
Ninu ọrọ rẹ, Oyetọla ṣalaye pe owo tijọba fẹẹ na (Recurrent Expenditure) jẹ biliọnu lọna mẹtalelaaadọta o le diẹ (#53.5b), nigba ti owo ti yoo wọle (Capital Expenditure) le diẹ ni biliọnu lọna aadọrin (#76.1b).
Oyetọla sọ siwaju pe biliọnu mẹrindinlọgbọn naira (#26.6b) ni yoo lọ sori eto-ẹkọ, biliọnu lọna mọkandinlogun naira (#19b) nijọba yoo na lori idagbasoke awọn nnkan amayedẹrun, biliọnu meje naira (#7b) ni yoo si wa fun iṣẹ agbẹ.
Gomina salaye pe afojusun bọjẹẹti ọhun wa lati tun mu ki owo to n wọle funjọba labẹnu rugọgọ si i, ki awọn araalu si maa jẹgbadun ijọba siwaju ati siwaju si i ninu iṣẹ idagbasoke kaakiri ilu.
O ni oniruuru igbesẹ nijọba ti gbe lati le wa ọna ti owo yoo maa gba wọle funjọba lai di ẹru wuwo le awọn araalu lori.
Gẹgẹ bo ṣe wi, “Gbogbo awọn ileewosan ijọba to wa kaakiri ipinlẹ yii nijọba yoo tun ṣe, bẹẹ ni atunṣe awọn oju-ọna yoo pọ lọdun 2022.
“Ko si iṣẹ kankan tijọba wa dawọ le ti yoo di aṣepati. A oo tubọ gbaruku ti ọrọ eto-aabo lati le mu ko rọrun fun awọn oludokoowo lati wa sipinlẹ Ọṣun.
“Igbesẹ ti a gbe laipẹ yii lori pe ki awọn amugbalẹgbẹẹ gomina atawọn oloṣelu maa wọ Adirẹ ni gbogbo ọjọ Tọsidee tun wa lara awọn ọna ti a fẹẹ gba mu igbelarugẹ ba aṣa ati iṣe nipinlẹ Ọṣun, a si nigbagbọ pe yoo yọri si gbajugbaja ọja nla ti awọn eeyan yoo ti ma a wa ra Adirẹ Ọṣun.’’
Ṣaaju ni Olori ileegbimọ aṣofin, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ti gboṣuba fun Gomina Oyetọla fun akoyawọ rẹ lori eto iṣuna ipinlẹ Ọṣun, ati bi ko ṣe ya oninaakunaa pẹlu owo kekere to n wọle sapo ijọba.
Owoẹyẹ ṣeleri pe awọn aṣofin yoo bẹrẹ iṣẹ kiakia lori aba eto iṣuna naa.