Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ile-ẹjọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu eto idibo, eyi to fikalẹ siluu Akurẹ, ti mu oṣu kẹrin, ọdun ta a wa yii, gẹgẹ bii ọjọ ti idajọ yoo waye lori ẹjọ ti oludije ẹgbẹ oṣelu PDP, Eyitayọ Jẹgẹdẹ pe, ta ko ọna ti ẹgbẹ APC fi fa Gomina Rotimi Akeredolu kalẹ bii oludije wọn ninu ibo ti wọn di lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja.
Alaga igbimọ olugbẹjọ ẹlẹni mẹta ọhun, Onidaajọ Umar Abubakar, lo fidi eyi mulẹ ninu ijokoo wọn to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.
Awọn agbẹjọro to n gba ẹnu sọ fun olupẹjọ, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, atawọn olujẹjọ mejeeji, Gomina Akeredolu pẹlu ajọ eleto idibo, ni wọn fun lanfaani ikẹyin lọjọ naa lati waa fidi ẹri ẹjọ wọn mulẹ niwaju igbimọ ọhun ki wọn too mu ọjọ idajọ.
Amofin agba Onyechi Ikpeazu to kọkọ dide sọrọ bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbẹjọro olujẹjọ ṣe n gbiyanju lati fẹnu tẹmbẹlu ohun to ṣe pataki ninu iwe ofin Naijiria.
O ni ohun to han kedere ni pe ọna ti ẹgbẹ oṣelu APC fi fa Akeredolu ati igbakeji rẹ, Lucky Aiyedatiwa, kalẹ gẹgẹ bii oludije lodi patapata sofin.
Agbẹjọro fun ajọ eleto idibo, Amofin Charles Edosomwan, ni ẹjọ ti oludije ẹgbẹ PDP pe ko lẹsẹ nilẹ rara nitori pe ko sohun to lodi sofin ninu ilana ti wọn fi yan gomina ọhun ati igbakeji rẹ.
Amofin ọhun rọ awọn igbimọ naa lati da ẹjọ ti Jẹgẹdẹ pe nu bii omi iṣanwọ, nitori pe ẹjọ ti ko lẹsẹ nilẹ ni.