Eto ikaniyan yoo mu igba ọtun wọ ilẹ Naijiria – Hundeyin 

Monisọla Saka

Kọmiṣanna ijọba apapọ fun ileeṣẹ eto ikaniyan nipinlẹ Eko, National Population Commission, (NPC), Amofin Abimbọla Salu-Hundeyin, ti sọ pe eto ikaniyan ọdun 2023 yii, ti yoo waye lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, si ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun yii, yoo jẹ atẹgun si awọn ohun meremere lorilẹ-ede Naijiria.

Hundeyin sọrọ yii nibi akanṣe eto kan ti wọn ṣe pẹlu awọn oniroyin nipinlẹ Eko lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii. Lajori ipade ọhun ni lati la awọn oniroyin lọyẹ lori ọna ti wọn le gba fọnrere eto ikaniyan ọdun yii fun tolori tẹlẹmu awọn olugbe ipinlẹ Eko lati gbọ, ati lati kopa.

Bakan naa lo sọ pe eto ikaniyan ọdun yii yoo yatọ si tawọn to ti n waye latẹyinwa, nitori awọn ohun eelo imọ ẹrọ tawọn yoo ṣamulo ati gbogbo ipalẹmọ tawọn ti n se lati ọdun 2016, o ni nitori idi eyi, ko ni i si tabi-ṣugbọn tabi kọnu-n-kọhọ kankan ninu abajade eto ikaniyan ọdun yii.

Hundeyin ni, “Imọ ẹrọ lọlọkan-o-jọkan, yatọ si oniwee ati beba lati ojule si ojule ti wọn n ṣe tẹlẹ, nileeṣẹ eto ikaniyan yoo ṣamulo lọdun 2023 yii. Eto EAD, ta a ti ṣe silẹ lati mọ awọn ile to wa lagbegbe kọọkan, ati ẹrọ ilewọ pelebe ti wọn n pe ni EADPAD, ta a ti pese silẹ yoo mu ko rọrun, nidii eyi, yoo ṣoro fun awọn oṣiṣẹ eleto ikaniyan lati fo ile kan, lai ka awọn eeyan to wa nibẹ, tabi ki wọn kọ ohun ti wọn ri silẹ gẹgẹ bii iye eeyan ti wọn ka.

“Gbogbo ile to wa lagbegbe kọọkan lo ti wa lori ẹrọ yii, ti wọn ba si tilẹ ti wo ile kan lapa ibi kan ṣaaju akoko naa, ẹrọ yii yoo fi han”.

Nigba to n ṣapejuwe eto ikaniyan bii afẹfẹ ti yoo jẹ kawọn ọmọ Naijiria ri nnkan mi simu, Hundeyin rọ awọn araalu lati kopa ninu eto ikaniyan yii, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu ajọ naa nigba to ba bẹrẹ. O ni lara anfaani ti eto ikaniyan yii yoo mu ba awujọ wa ni pe yoo jẹ ko rọrun fun ijọba lati pese awọn nnkan ta a nilo fun wa ninu ilu.

Bakan naa lo tun rọ awọn eeyan lati duro si agbegbe ibi ti wọn n gbe, ti wọn ti n jẹ, ti wọn ti n mu, ko le rọrun fawọn oṣiṣẹ eleto ikaniyan lati mọ iye eeyan to n gbe ninu ilu kan. O ni awọn eeyan ti wọn maa n lọ siluu wọn nitori ki iye eeyan to wa labule wọn le pọ, maa n ṣe akoba fun eto yii, nitori nigba ti wọn ba pada sibi ti wọn n gbe ninu igboro, akoba nla ni fun ọrọ aje ati eto ti ijọba ni fun agbegbe ibẹ.

Niwọnba igba to ti jẹ pe ijọba yoo kede isinmi lakooko naa, o rọ awọn eeyan lati duro sile. Yatọ sawọn ti wọn n ṣeto ikaniyan, awọn oniroyin yoo maa lọ kaakiri, awọn oṣiṣẹ eleto ilera atawọn mi-in ti iṣẹ wọn pe fun ki wọn ma fi taratara gbele lo ni yoo wa nita.

Lori ọna ti wọn yoo gbe ọrọ awọn ti ko rile gbe atawọn alarun ọpọlọ gba, o ni, “Lara eto to ti wa nilẹ ni ohun ta a n pe ni ‘alẹ eto ikaniyan’, nipinlẹ Eko nibi, niwọnba igba ti agbegbe kọọkan, ile atawọn nnkan mi-in ti wa lori ẹrọ ta a n wi yii, alẹ, nigba ti wọn ti dari sibi ti wọn yoo sun si la maa ka wọn”.

Leave a Reply