Ẹwọn n run nimu Ariyọ yii o, apo igbo ni wọn ka mọ ọn lọwọ n’Iyin-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Afaimọ ki ọkunrin ẹni aadọta ọdun kan, Ọgbẹni Oluwole Ariyọ, ma fẹwọn jura pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe wọ ọ wa sile-ẹjọ Majisreeti  kan to wa ni Ado-Ekiti. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe wọn ka apo igbo kan mọ ọn lọwọ.

Agbefọba to mu ẹsun afurasi ọdaran naa wa si kootu, Isipẹkitọ  Olubu Apata, sọ pe Ariyọ ṣẹ ẹṣẹ ti wọn tori ẹ wọ ọ wa si kootu yii lọjọ kẹsan-an, oṣu Karun-un, ọdun 2023, ni deede aago kan ọsan ni ilu Iyin-Ekiti, nijọba ibilẹ Irẹpọdun/Ifẹlodun, nipinlẹ naa.

Ọdaran naa ti awọn ọlọpaa ti kọkọ da duro si agọ wọn, nibi ti wọn ti f’ọrọ wa a lẹnu wo, ni wọn ka apo kan to kun fun igbo mọ  ọn lọwọ, ti ko le si le ṣalaye ibi pato ibi to ti ri igbo naa.

Apata ni iwa ti olujẹjọ naa hu lodi sofin gbigbe egboogi oloro to jẹ ofin ipinlẹ Ekiti, ti wọn kọ nipinlẹ naa lọdun 2005.

O bẹ kootu pe ki wọn fi ọdaran naa pamọ si ọgba ẹwọn titi di akoko diẹ ti oun yoo fi ri aaye ko awọn ẹlẹrii oun wa sile-ẹjọ naa, ati ki oun le raaye wo awọn faili ẹjọ naa daradara.

Nigba to n fesi si ẹsun ti wọn fi kan an, Ariyọ ni oun ko jẹbi ẹsun ti awọn ọlọpa fi kan oun naa. Bakan naa ni agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Tunmiṣe Akinwunmi, rọ ile-ẹjọ pe ki wọn fun onibaara oun ni beeli pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ, yoo duro lati jẹ ẹjọ naa.

Ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Taiwo Ajibade, gba beeli ọkunrin naa pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira ati oniduuro kan.

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2024.

Leave a Reply