Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọkunrin kan, Kposu Benjamin, ti dero ọgba ẹwọn bayii, ile-ẹjọ lo paṣẹ bẹẹ latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ko ibalopọ fọmọ ọdun mẹtadinlogun ti wọn forukọ bo laṣiiri kan.
Adajọ A.I. Adeniyi tile-ẹjọ Majisreeti to fikalẹ siluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lo juwe ọna ọgba ẹwọn Mandala fun afurasi ọdaran ọhun lasiko igbẹjọ rẹ to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.
Agbefọba, Abdullahi Sanni, to ṣoju fun olupẹjọ sọ ni kootu naa pe ileeṣẹ ti wọn ti n ṣe omi inu ike ti orukọ rẹ n jẹ (Motis Table Water), ni ọkunrin afurasi yii ti n ṣiṣẹ ọde, to si fi tipatipa ko ibalopọ fun ọmọbinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun, kan to tun ṣe e basubasu lagbegbe Gaa-Akanbi, Ilọrin, nipinlẹ Kwara.
O ni Bamikaye Kayọde to jẹ oṣiṣẹ ẹṣọ alaabo ileeṣẹ kan ti wọn pe ni (Illumination) lo mu ẹjọ Benjamin wa si teṣan awọn, kawọn agbofinro too bẹrẹ iwadii. Wọn gbe ọmọbinrin naa lọ si ileewosan kan lagbegbe Gaa-Akanbi, niluu Ilọrin, ti awọn dokita si fidi ẹ mulẹ pe afurasi naa huwa buruku naa loootọ.
O ni ẹṣẹ tọkunrin naa da ta ko isọri ọrinlerugba o le mẹta (283) iwe ofin ilẹ wa. Sanni tẹsiwaju pe wọn ti fi iwe ẹsun rẹ sọwọ si ẹka to n ṣe iwadii nipa iwa ọdaran, eyi to n ri si awọn to n ṣe fayawọ obinrin ati ọmọde.
Adajọ A.I. Adeniyi ni ki wọn taari ẹ sọgba ẹwọn Mandela na, o si sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kẹjọ, oṣu kejila.