Tanka epo gbina n’Ibadan, ọkọ mẹta jona guruguru

Ọlawale Ajao, Ibadan

Tanka epo nla kan pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ meji lo ṣegbe sinu ijanba ina kan lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii nigboro Ibadan, loju ọna Eko.

Ijanba ọhun lo waye nigba ti ọkọ tanka epo kan deede ṣubu lulẹ, to si gbina lẹsẹkẹsẹ ni nnkan bii aago mọkanla alẹ.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ko pẹ pupọ ti ajalu yii bẹrẹ lawọn panapana debẹ ti wọn si pana ọhun bo tilẹ jẹ pe ọkọ ta ka epo yii pẹlu ọpọ dukia mi-in ti ṣegbe sinu ijanba naa ki Ọlọrun to fun wọn ni aṣeyọri naa ṣe.

Oludari eto iṣọwọ-ṣiṣẹ ileeṣẹ panapana ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ismail Adeleke, fidi ẹ mulẹ pe lati inu ẹnjinni ọkọ nla naa nina ọhun ti ṣadeede ṣẹ yọ.

O ni eyi lo mu ki awakọ yii sare bẹ silẹ lati inu mọto naa lai tilẹ ni suuru ki ọkọ naa duro.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Bi tanki epo ọkọ yẹn ṣe bẹ ni bẹtiroolu n ṣan loju titi, ti ina si n tẹlẹ agbara epo naa nibikibi to ba gba lọ.

“Titi di aago mọkanla aabọ alẹ ana Ia ṣi wa nibi taa ti n gbiyanju lati pana yẹn.

“A dupẹ pe iṣẹlẹ yẹn ko gbẹmi eeyan kankan ṣugbọn Tanka epo yẹn pẹlu ọkọ ayọkẹlẹ meji jona kọja atunṣe.”

Leave a Reply