Ọlawale Ajao, Ibadan
Atimọle awọn ẹṣọ alaabo ilu, iyẹn Nigeria Security and Civil Defence Corps, NSCDC, n’Ibadan, lo ṣe e ṣe ki Ajihinrere Francis Abayọmi, ti ṣe jẹ gbogbo iṣẹ ihinrere rẹ lati asiko yii di ipari oṣu kin-in-ni, ọdun 2021 yii, nitori bo ṣe fi tipa tikuuku laṣepọ pẹlu ọmọdebinrin ti ko ju ọmọ ọdun meje lọ.
Baba ẹni ọdun mejidinlọgọta (58) yii la gbọ pe o fi ọgbọn alumọkọrọyi tan ọmọbinrin naa, Monday Dorcas, ẹni ta a fi ojulowo orukọ ẹ bo laṣiiri lọ si ojú-ọlọ́mọ-ò-tó-o, to si fi kinni nla fa ọmọọlọmọ labẹ ya nipasẹ ibalopọ.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, to lọ lọhun-un niṣẹlẹ ọhún waye l’Opoopona Kutamiti, lagbegbe Bódìjà, n’Ibadan.
Irin yẹnku yẹnku ti Dorcas rin lọ sile pẹlu ẹjẹ to kún gbogbo oju ara ẹ lo tu pasitọ laṣiiri nigba ti iya fi dandan le e pe ko jẹwọ ẹni to da ọgbẹ si i nibi kọlọfin ara.
Iya Dorcas, pẹlu awọn alabaagbe ẹ ko mọ oju ti wọn fi lọọ já bá pasitọ ti oun naa jẹ aladuugbo wọn nile. Bo tilẹ jẹ pe oluṣọ-aguntan naa ko ti i jẹwọ ẹṣẹ rẹ fawọn eeyan, sibẹ, awọn obi ọmọ naa ko fi ọ̀wọ̀ iṣẹ ihinrere to yan laayo wọ ọ ti wọn fi fa a le awọn agbofinro lọwọ.
Olu-ileeṣẹ ajọ sifu difẹnsi ipinlẹ Ọyọ to wa laduugbo Agodi, n’Ibadan, ni wọn mu ẹjọ Francis lọ taara.
Lẹyin iwadii, Ọgbẹni Iskilu Akinsanya ti i ṣe ọga agba awọn ajọ NSCDC ko jẹ ko pẹ lọdọ wọn rara ti wọn fi pe e lẹjọ si kootu ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni Iyaganku, n’Ibadan.
Onidaajọ S.H. Adebisi ti i ṣe adajọ ile-ẹjọ Majisireeti ọhun ti waa paṣẹ pe ki wọn fi olujẹjọ iwa ọdaran naa pamọ si atimọle ajọ sifu difẹnsi titi di ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, nigba ti igbẹjọ naa yoo maa tẹsiwaju.