Ẹwọn n run nimu Samuel at’ọrẹ ẹ yii o, awọn kan ni wọn lọọ lu ni jibiti owo nla l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Afaimọ ki awọn ọrẹ meji yíì, Oluwadaisi Samuel, ẹni ọdun mejilelogoji (42), ati ọrẹ rẹ, Innocent  Ọsadare, ẹni ọdun mọkandinlogoji, ma ṣewọn pẹlu bi awọn ọlọpaa ṣe wọ wọn lọ si ile-ẹjọ Majisreeti kan nipinlẹ Ekiti lori ẹsun jibiti lilu.

Gẹgẹ bi Agbefọba, Isipẹkitọ Surdiq Adeniyi, ṣe sọ, o ni awọn ọdaran mejeeji yii ti wọn jẹ ọrẹ ni wọn ṣẹ ẹṣẹ yii lọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Ado-Ekiti.

O ni niṣe ni wọn fi ọgbọn alumọkọrọyi gba owo to to bii ẹgbẹrun lọna ọgọfa Naira lọwọ ọkunrn kan, Adewale Adeṣẹwa, lọna ti ko ba ofin mu.

Pọsikutọ yii ṣalaye siwaju si i pe bakan naa ni awọn meji yii tun fi ọgbọn jibiti gba owo to din diẹ ni irinwo Naira lọwọ (380, 000) lọwọ Arabinrin Aanuoluwapọ Famuagun, pẹlu ọgbọn pe wọn yoo fi ṣọọbu ati ile oju ile kan to jẹ ile aladaagbe kan fun un.

Pọsikutọ yii ṣalaye pe ẹsun wọnyi lodi sofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2021. O sọ pe oun ṣetan lati pe ẹlẹrii to to bii marun-un wa si ile-ẹjọ naa lati le waa jẹrii si ọrọ naa.

Ṣugbọn o tọrọ aaye ranpẹ lọwọ ile-ẹjọ naa pe eleyii yoo fun oun ni anfaani lati le ko awọn ẹlẹrii oun jọ, ki wọn le waa jẹrii si ọrọ naa, ati ki oun le ri akoko lati le fi ọkan balẹ wo faili ẹjọ naa.

Ṣugbọn awọn ọdaran mejeeji yii ni wọn sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun naa. Bakan naa ni awọn agbẹjọro awọn mejeeji, Ọgbẹni Fẹmi Ọlarewaju ati Gboyega Abiọla, rọ ile-ẹjọ naa pe ko yọnda onibaara wọn, wọn si ṣeleri pe wọn ko ni i sa lọ, wọn yoo duro lati gbọ igbẹjọ naa.

Ṣugbọn ninu idajọ rẹ, Onidaajọ Dọlamu Babalogbọn fun awọn ọdaran naa ni iyọnda pẹlu iye owo to to bii ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un pẹlu ẹlẹrii kọọkan. Ẹyin eyi lo sun igbẹjọ naa siwaju di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2024.

Leave a Reply