Lati Benue lawọn ọrẹ meji yii ti ji ọmọ gbe, ipinlẹ Eko lọwọ ti tẹ wọn

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lawọn ọrẹ meji kan, Tewase Peter ati Ternugwa Paul, ti wọn ti jingiri ninu iṣẹ ijinigbe nipinlẹ Benue wa. Awọn ọmọde meji kan ni wọn ji gbe lati ipinlẹ Benue lọhun-un, ti wọn fẹẹ ta wọn si orileede Ghana fun okoowo ẹru lowo pọọku, ṣugbọn ti ọwọ awọn agbofinro tẹ wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lagbegbe Itaoluwo, niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko.

ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn afunrasi ọdaran ọhun lọọ ji awọn ọmọ meji kan, Precious ati Agera, gbe lakata awọn obi wọn. Asiko tawọn obi wọn lọ sọja ni wọn ji wọn gbe wa siluu Eko lati ta wọn lowo pọọku silẹ Ghana.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun akọroyin wa lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe ko sibi tawọn obi awọn ọmọ naa ko wa wọn de ni gbara ti wọn ti ọja de ti wọn ko ri wọn nibi ti wọn fi wọn si.

Gbogbo akitiyan obi awọn ọmọ naa lati pe sori foonu awọn ọmọ wọn lati mọ ibi ti won wa lo ja si pabo nitori pe ṣe ni awọn afunrasi ọdaran ọhun ti lu foonu wọn pa patapata. Ṣugbọn alaaanu kan to mọ nipa ohun tawọn oniṣẹẹbi naa fẹẹ fawọn ọmọ ọhun ṣe nilẹ ajoji lo gbe ipe awọn obi awọn ọmọ naa lasiko tawọn ọdaran ọhun ko si nile, to si ṣalaye ibi tawọn ọmọ yii wa ati ohun ti wọn fẹẹ fi wọn ṣe fun wọn.

Loju-ẹsẹ lawọn obi awọn ọmọ naa ti pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, tawọn yẹn si tete bẹrẹ iwadii abẹnu nipa iṣẹlẹ ọhun. Ọwọ pada tẹ awọn afurasi ọdaran ọhun nibi ti wọn wa, wọn si fi akolo ofin mu wọn ju sahaamọ awon ọlọpaa loju-ẹsẹ.

Alukoro ni awọn ko ni i faaye gba iwa ọdaran laarin ilu Eko, ati pe iba daa kawọn ọdaran tete fi ilu Eko silẹ ni kia, bi bẹẹ kọ, wọn maa kan idin ninu iyọ.

O ni awọn maa foju wọn bale-ẹjọ lẹyin tawọn ba pari iwadii awọn tan nipa.

Leave a Reply