Faith Adebọla, Eko
Esi lẹta ẹwọn ti Oluwasunkanmi Alatiṣe ati Oluwaṣẹgun Ologbe n kọ nidii okoowo fifi awọn ọmọ ọlọmọ ṣowo ẹru ti de o, ẹwọn ọdun mejilelogun lo ba de fawọn mejeeji, lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Ajọ kan tijọba apapọ da silẹ ta ko aṣa kiko awọn ọmọ ọlọmọ lọọ ṣe ẹru, ọmọọdọ tabi iṣẹ aṣẹwo, ati lati ja fun ẹtọ awọn ọmọ ti wọn ba ṣe bẹẹ fun (National Agency for Prohibition of Trafficking in Person), NAPTIP, lo wọ awọn afurasi ọdaran naa lọ si ile-ẹjọ lọdun 2017, pe wọn jẹbi fifi awọn ọmọge meji kan, Okeda Mercy ati Alatiṣe Bọla, ṣọwọ sorileede France, fun iṣẹ aṣẹwo.
Bo tilẹ jẹ pe awọn mejeeji sọ pe awọn o jẹbi, ti agbẹjọro wọn si ti n ṣe atotonu siwaju sẹyin lati da wọn lare, adajọ ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun akanṣe ati iwa ọdaran abẹle nipinlẹ Eko, Onidaajọ Abdul-Azeez Anka, sọ pe awijare awọn olujẹjọ naa ko tẹwọn rara, o si da gbogbo atotonu wọn nu bii omi iṣanwọ.
Adajọ naa ni gbogbo ẹri to wa niwaju ile-ẹjọ naa fihan kedere pe iṣẹkiṣẹ lawọn afurasi ọdaran mejeeji ti wọn fẹsun kan naa n ṣe, wọn si jẹbi awọn ẹsun mẹtẹẹta ti wọn fi kan wọn. Awọn ẹsun naa ni pe wọn gbimọ-pọ lati huwa ibi, wọn lu jibiti, wọn n pe ara wọn ni ohun ti wọn ko jẹ, wọn si n ṣagbatẹru iṣẹ aṣẹwo.
Adajọ ni olupẹjọ ti ṣe bẹbẹ lati fi ẹri to daju gbe awọn ẹjọ naa lẹsẹ, tori lọrọ awọn olujẹjọ naa ko ṣe ta leti oun. Latari eyi, o ni ki ọkọọkan wọn ṣẹwọn ọdun marun-un fun ẹsun akọkọ, ki wọn si ṣẹwọn ọdun meje fun ẹsun keji, aropọ ọdun mọkanla fun afurasi ọdaran kọọkan.
O ni ki wọn bẹrẹ si i ka ẹwọn wọn latigba ti wọn ti fi pampẹ ofin gbe wọn.