Lẹyin ọsẹ meji ti awọn agbofinro da Sunday Igboho lọna, awọn kan tun fẹẹ pa awọn ọmọ ẹ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

 

Lẹyin ọsẹ meji ti awọn agbofinro da ajafẹtọọ ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho) lọna, ṣugbọn ti wọn gbe e ju silẹ nitori ti apa wọn ko ka a, awọn ẹruuku kan tun da awọn ọmọ ẹyin ẹ lọna pẹlu erongba lati pa wọn.

Lasiko ti ajafẹtọọ Yoruba naa ran awọn ẹmẹwa ẹ yii nisẹ lawọn afẹmiṣofo naa fẹẹ gbẹmi wọn soju ọna nigboro Ibadan pẹlu awọn nnkan ija oloro lọjọ Ẹtì, Furaidee, ọsan yii.

Meji ninu awọn afurasi ọdaran naa ni wọn wọ aṣọ soja, bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le fidi ẹ mulẹ boya ojulowo ọmọọgun ilẹ yii ni wọn.

Ṣugbọn awọn tọọgi ọhun ba awọn ọmọ ẹyin Igboho lakọ bii ibọn. Lẹyin ọpọlọpọ ija laarin ikọ mejeeji, awọn ọmọ Sunday Igboho fẹyin awọn ọmoogun ọlọtẹ balẹ, wọn si fa wọn le awọn agbofinro lọwọ.

Ki i ṣe pe wọn ṣẹgun awọn ọdaran ọhun nikan, niṣe ni wọn palẹ mẹta mọ ninu wọn laaye, wọn si lọọ gbe wọn ba ọga wọn, Igboho Ooṣa, funra ẹ nile.

Lọgan niyẹn ti paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ si agọ ọlọpaa lati fa wọn le awọn agbofinro lọwọ.

Agọ ọlọpaa Sanyo, n’Ibadan, ti ko jinna sile Sunday Igboho laduugbo Soka, lawọn afurasi ọdaran naa wa titi ta a fi parí akojọ iroyin yii. Aṣọ ologun ni meji ninu wọn wọ, nigba ti awọn meji yooku jẹ tọọgi paraku.

Akitiyan wa lati fidi iroyin yii mulẹ lolu Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ko seso rere pẹlu bi akọroyin wa ko ṣe ri CSP, Olugbenga Fadeyi, ti i ṣe agbẹnusọ wọn ba sọrọ titi ta a fi parí akojọ iroyin yii.

Leave a Reply