Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Adajọ ile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Oṣogbo ti ju Tunde Oyedokun, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, sẹwọn ọdun mẹwaa lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ọdun mẹtala lo pọ.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2019, ni Tunde kọkọ fara han ni kootu, latigba naa lo si ti wa lọgba ẹwọn ilu Ileṣa, ko too di pe wọn gbe e wa si kootu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Aagbefọba to gbe Tunde wa si kootu, Abiọdun Fagboyinbo, ṣalaye pe ninu oṣu kẹrin, ọdun 2019, ni olujẹjọ huwa naa loju-ọna Balogun, lagbegbe Omigade, niluu Oṣogbo.
Lọjọ naa ni wọn ni Tunde fipa ba ọmọdebinrin naa lo pọ, eleyii to si lodi si ipin okoolelugba o din meji (218) ninu abala ikẹrinlelọgbọn ofin iwa ọdaran ti ọdun 2003 tipinlẹ Ọṣun n lo.
Lẹyin ti olujẹjọ sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa ni adajọ Majisreeti naa, Modupẹ Awodele, sọ pe agbefọba ti fidi ẹsun naa mulẹ daadaa.
Nitori naa, o han gbangba pe olujẹjọ jẹbi ẹsun yii, lo ba ju u sẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun akọkọ, bakan naa lo ju u sẹwọn ọdun mẹwaa fun ẹsun keji, ṣugbọn o ni ko ṣe ẹwọn naa lẹẹkan naa.