Ẹwọn ọdun mọkanlelogun ni darandaran to ba gbebọn dani maa fi jura l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko

Ileegbimọ aṣofin Eko ti bẹrẹ si i ṣe atupalẹ abadofin tuntun ti wọn fẹẹ fi de fifi maaluu jẹko ni gbangba jake-jado ipinlẹ naa, ẹwọn ọdun mọkanlelogun ni wọn dabaa pe ki wọn sọ darandaran eyikeyii ti wọn ba ka ibọn mọ lọwọ si.

Ọjọ Aje, Mọnde, lawọn aṣofin naa din isinmi wọn ku, ti wọn si wọle apero gẹgẹ bii iṣe wọn lati jiroro lori abaofin naa.

Eyi ni igba keji ti ijiroro maa waye lori abadofin ọhun, eyi ti Gomina Babajide Sanwo-Olu ti fi sọwọ si wọn ṣaaju.

Lasiko ijiroro ọhun, awọn aṣofin Eko koro oju si bawọn darandaran kan ṣe maa n da maaluu kiri igboro Eko, ti wọn si maa n fi maaluu jẹko lori ilẹ onilẹ lawọn agbegbe kan, wọn lawọn ẹran ọsin ọhun si tun maa n ba ire-oko awọn agbẹ jẹ, yatọ si ti oorun ati ẹgbin ti igbọnsẹ wọn maa n ṣe saduugbo tawọn eeyan n gbe.

Ọnarebu Bisi Yusuff to n ṣoju awọn eeyan Alimọṣọ sọ pe inu oun dun si abadofin yii, oun si nireti pe yoo di ofin laipẹ, o ni ofin to yẹ ko ti maa ṣiṣẹ tipẹ ni ta a ba wo adanu ati ipenija ti fifẹran jẹko ni gbangba ti mu ba awọn eeyan ipinlẹ Eko ati ilẹ Yoruba lapapọ.

O ni: “Emi fọwọ si i, koda mo fi gbogbo ara si i pe ki wọn ṣedajọ ẹwọn ọdun mọkanlelogun fun ẹnikẹni to ba pera ẹ ni darandaran, ṣugbọn to n gbe nnkan ija oloro kiri, paapaa ibọn. Iwa buruku tawọn darandaran n hu nilẹ Yoruba ti mu ki ounjẹ gbowo leri gegere.”

Ni ti ekeji rẹ, Ọnarebu Kẹhinde Joseph, toun naa ṣoju Alimọshọ, o ni “ko ṣe e maa gbọ seti, ko tiẹ yẹ ki wọn maa ba wa gbọ ọ pe nibi taye laju de yii, lọdun 2021 ni Naijiria ṣi wa ninu ijiroro fifi maaluu jẹko ni gbangba.’’ O ni abadofin yii maa mu ki alaafia ati ajọṣe to danmọran wa laarin awọn agbẹ ọlọsin-ẹran ati awọn to n gbin ire-oko, ati pe yoo din iwa ọdaran atawọn iwakiwa mi-in to n waye lawujọ ku. “Niṣe lemi fẹẹ parọwa sawọn agbofinro wa pe ki wọn ba wa fọwọ pataki mu ofin yii to ba ti bẹrẹ iṣẹ, ọrọ ṣereṣere kọ o,” Joseph lo sọ bẹẹ.

Lara awon aṣofin mi-in ti wọn sọ ero wọn jade lori abadofin yii ni Ọnarebu Lukmọn Olumọ lati Ajerọmi-Ifẹlodun, Ọnarebu Wale Rauf lati Amuwo-Ọdọfin, Ọnarebu Gbọlahan Yishawu lati Eti-Ọsa ati Ọnarebu Abiọdun Tọbun lati agbegbe Ẹpẹ. Gbogbo wọn ni wọn dunnu si abadofin naa.

Abẹnugan wọn, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa sọ pe ipinlẹ Eko ko ni i pẹ darapọ mọ awọn gomina ipinlẹ Guusu ilẹ wa ti wọn pinnu pe ofin ta ko fifi maaluu jẹko ni gbangba gbọdọ bẹrẹ iṣẹ lawọn ipinlẹ Guusu. O ni abadofin naa maa sọ ọ di dandan fawọn darandaran lati lọọ forukọsilẹ lọdọ ijọba ka le mọ pato ẹni to n da ẹran ati ibi to n da ẹran naa lọ.

Nipari, wọn taari abadofin naa si igbimọ alabẹ ṣekele lori iṣẹ agbẹ ati ẹgbẹ alafọwọsowọpọ pe ki wọn tubọ lọọ ṣiṣẹ lori awọn aba ti wọn gbọ, ki wọn si jẹ kawọn araalu naa fi aba ati erongba wọn lori abadofin yii kun un.

Leave a Reply