Ewure lawọn gende yii lọọ ji tọwọ fi tẹ wọn n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọbọ, Tọsidee, ọṣẹ yii, lọwọ palaba awọn ọkunrin meji yii segi lasiko ti wọn lọọ ji awọn ẹran ewurẹ ko lagbegbe Federal Low Cost Estate, Ọlọjẹ, Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ti n ṣẹju pako ni akolo ọlọpaa bayii.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mẹjọ aabọ owurọ kutu, Ọjọbọ, ti awọn ogboju ole naa ri i pe adugbo ti da, ti onikaluku ti gba ibi iṣẹ oojọ rẹ lọ ni wọn gbe ọkọ ayọkẹlẹ Họnda alawọ dudu wọ agbegbe naa, wọn mu agbado lọwọ, wọn si n da a silẹ lati fi fa oju awọn ẹran ọhun mọra. Bi wọn ṣe n da agbado silẹ ni wọn n nawọ gan awọn ẹran yii, ti wọn si ko wọn sinu ọkọ wọn. Bi wọn ṣe n ṣe eyi ni arakunrin kan n wo wọn lọọọkan, bo ṣe sun mọ wọn lo pariwo ‘ole’, ole eyi lo mu ki gbogbo adugbo tu jade. Awọn ole naa fẹẹ maa sa lọ, ṣugbọn taya ọkọ naa gun eso, ni ọwọ ba tẹ awọn jagunlabi.

Alaaji ni awọn mejeeji, wọn ja wọn si ihoho, wọn tun ba gbogbo ọkọ wọn jẹ patapata. Lẹyin eyi ni wọn fa awọn mejeeji le ọlọpaa lọwọ fun ẹkunrẹrẹ iwadii. Ṣugbọn afurasi adigunjale ọhun sọ pe ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ ni ọrọ naa, o ni awọn o ṣẹṣẹ maa ji ewurẹ gbe, ṣugbọn awọn ba onile nile lọjọ naa lọwọ ṣe tẹ awọn.

 

Leave a Reply