Faith Adebọla
Afaimọ ki ipinlẹ Kaduna ma gba oye ipinlẹ ti aabo rẹ mẹhẹ ju lọ lorileede yii pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, latari bi iwa janduku, ijinigbe ati ipaniyan ṣe n legba kan si i lojoojumọ nibẹ, odidi ọba alaye ti wọn n pe ni Ẹmia, ti ilu Kajuru, Alaaji Alhassan Adamu lawọn janduku agbebọn tun ji gbe pẹlu awọn mẹwaa mi-in.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ipinlẹ Kaduna fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro wọn, Muhammed Jalige, sọ pe loootọ lawọn ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii, o waye loru mọju ọjọ Aiku, Sannde yii.
Jalige ni awọn agbebọn naa tun ji awọn eeyan mẹwaa mi-in ti wọn n gbe laafin Ẹmia naa gbe, lara wọn si jẹ aladuugbo ilu Kajuru.
O ni fẹẹrẹ owurọ yii ni iroyin naa to awọn ọlọpaa leti, wọn sọ fawọn pe nnkan bii aago meji oru lawọn agbebọn naa wa, ati pe ibọn ni wọn yin lati fi ja ilẹkun aafin ti wọn fi raaye wọle ṣiṣẹ buruku wọn.
O tun ṣalaye pe awọn ọlọpaa ti bẹrẹ si i lepa wọn bayii, bẹẹ lawọn ti kan sawọn ṣọja pẹlu, ki wọn le ri ọba naa atawọn eeyan yooku gba pada lai fara pa.
Wọn lobinrin mẹta lo wa ninu awọn ti wọn ji gbe yii, ọmọọmọ Ẹmia naa meji, ati mẹta lara awọn oṣiṣẹ aafin rẹ.
Ẹnikan to ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin iṣẹlẹ yii sọ pe mejila lawọn ti wọn ji gbe, ki i ṣe mẹwaa. O ni niṣe lawọn janduku agbebọn naa ṣina ibọn bolẹ loru nigba ti wọn de, ko si sẹni to foju kan oorun titi tilẹ fi mọ, tori ariwo ati girigiri ẹsẹ wọn lo gbode, inu ibẹru ati ipaya si lawọn araalu wa.
Tẹ o ba gbagbe, oru mọju Satide, Abamẹta, to ṣaaju eyi, awọn agbebọn ji eeyan mẹfa gbe ni ilu Milgoma, ijọba ibilẹ Sabon Gari, ni Kaduna.
Obinrin mẹta ati ọmọde mẹta ni wọn ji gbe lọjọ naa, ko si ti i sẹni to gbọ ohunkohun nipa wọn, bẹẹ ni wọn o ti i mọ inu igbo ti wọn gbe wọn pamọ si.
Ba a ṣe gbọ, ori lo ko ọlọkada kan yọ nigba ti iṣẹlẹ naa n waye, o n dari bọ lati ibiiṣẹ oojọ rẹ ni, ṣugbọn nitori ọkada rẹ yọnu loju ọna, niṣe lo n yi ọkada naa bọ nile ko too ko si wọn lọwọ, ti wọn si yinbọn fun un nigba to n sa lọ, ibọn naa ba a lapa, bo tilẹ jẹ pe o papa sa lọ.