Sound Sultan, olorin taka-sufee, ku lojiji

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Abduganiu Ọlanrewaju Fasasi gan-an lorukọ ẹ, ṣugbọn Sound Sultan lọpọ eeyan mọ ọkunrin olorin taka-sufee to ku lojiji lọjọ Sannde, ọjọ kọkanla, oṣu keje, ọdun 2021 naa si. Ẹni ọdun mẹrinlelogoji (44) ni.

Aarọ kutu ọjọ Sannde naa ni awọn mọlẹbi Sound Sultan, ẹni to kọ orin kan ti wọn n pe ni ‘Jagbajantis’, kede pẹlu ẹdun ọkan pe iku ti mu ọkunrin naa lọ lẹyin aisan ọlọjọ pipẹ to n ba a finra.

ALAROYE gbọ pe jẹjẹrẹ ọna ọfun ( Throat cancer) lo ti n daamu oloogbe yii fungba diẹ sẹyin, ki kinni naa too pada ja siku fun un lorilẹ-ede Amẹrika to ti n gbatọju.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu kọkanla, ọdun 1976, ni wọn bi Oloogbe Abdulganiu Ọlanrewaju Fasasi, niluu Jos, nipinlẹ Plateau, ṣugbọn ọmọ ipinlẹ Ọyọ gan-an ni. Akọrin ni, oṣere ni, alawada ni pẹlu, bẹẹ lo si maa n ba awọn olorin ka orin wọn silẹ lọna ti wọn ba fẹ.

Ni 2009, Sound Sultan ṣegebyawo pẹlu afẹsọna rẹ ti wọn ti jọ wa tipẹ, ọmọ Ibo lobinrin naa, Chichi Morah lo n jẹ. Ṣugbọn nigba to diyawo Sultan, o yi orukọ rẹ pada si Farida Fasasi. Ọmọ mẹta ni wọn bi funra wọn. Iyawo yii atawọn ọmọ naa pẹlu awọn ẹbi ni oloogbe fi saye lọ.

 

Leave a Reply