Awọn ajinigbe yinbọn pa Olori-ọdọ n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn ajinigbe tun ṣe bẹbẹ n’Ibadan lọjọ Abamẹta, Satide, pẹlu bi wọn ṣe yinbọn pa ọga awọn ọdọ nijọba ibilẹ Akinyẹle, n’Ibadan.

Ṣaaju, iyẹn ni ọsẹ to kọja yii, lawọn ọbayejẹ ẹda ti ọpọ eeyan ro si awọn Fulani darandaran yii ji ẹnikan gbe labule Akinkunmi, to wa nitosi Kaara, l’Akinyẹle, n’Ibadan.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ẹni ti wọn ji ọhun l’olori-ọdọ atawọn meji mi-in jọ n wa kiri inu igbo ti wọn fi ṣe kongẹ awọn ajinigbe ọhun, ti awọn ẹni ibi naa fi yinbọn lu wọn.

Olori-Ọdọ nikan nibọn ba nibi to lewu pupọ lagọọ ara, to si ṣe bẹẹ dero ọrun lẹsẹkẹsẹ, nigba ti awọn yooku fara pa.

Bo tilẹ jẹ pe akọroyin wa ko ri DSP Adewale Ọṣifẹṣọ ti i ṣe agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ba soro lori iṣẹlẹ yii, ALAROYE gbọ pe wọn ti ri ọkan ninu awọn afurasi ajinigbe ọhun mu.

 

Agọ ọlọpaa to wa ni Mọniya, nigboro Ibadan, lọkunrin naa wa titi ta a fi pari akojọ iroyin yii.

Leave a Reply