Awọn eleyii fẹẹ gba miliọnu mẹta aabọ lọwọ obi ọmọ ọdun mẹjọ ti wọn ji gbe l’Ogere

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta                  

To ba ṣe pe aṣiri ko tu ni, ti wọn ri miliọnu mẹta aabọ naira (3.5m) ti wọn n beere lọwọ obi ọmọ ọdun mẹjọ ti wọn ji gbe gba, awọn eeyan marun-un tẹ ẹ n wo yii ko ba ti maa ṣe faaji aye wọn kiri bayii. Ṣugbọn eto ti wọn ṣe ko to, awọn ọlọpaa ti mu wọn lọjọ kẹsan-an, oṣu keje yii, l’Ogere, ti wọn ti ji ọmọkunrin kan, Sadiq Abass, tọjọ ori ẹ ko ju mẹjọ lọ gbe.

Orukọ awọn ajọmọgbe naa ree bawọn ọlọpaa to foju wọn han ṣe pe e :Abdul Raman Umar, Falalu Abubakar, Danjuma Bako, Idris Lawal ati Fauziya Falalu.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa Ogun to  fiṣẹlẹ naa ṣọwọ s’ALAROYE ṣalaye pe baba ọmọ ti wọn ji gbe, Ọgbẹni Rilwan Mohammed, lo mu ẹjọ lọ si teṣan ọlọpaa Ogere, pe alaafia loun fiyawo atawọn ọmọ oun mẹta silẹ nile lọjọ naa ni nnkan bii aago mejila ọsan, koun too jade lọ.

Rilwan ni afi boun ṣe gba ipe kan. O loun ko mọ nọmba naa tẹlẹ, ṣugbọn ẹni to pe sọ pe awọn ti ji Sadiq gbe o, boun ba si fẹẹ ri i pada laaye, koun tete fi miliọnu mẹta aabọ ranṣẹ. Aijẹ bẹẹ, ọmọ naa ti lọ raurau niyẹn o.

Ifisun rẹ yii lawọn ọlọpaa bẹrẹ si i ṣiṣẹ le lori, DPO Ogere, CSP Abiọdun Ayinde, atawọn eeyan ẹ bẹrẹ iṣẹ iwadii ti wọn fi pada mọ ibuba awọn to ji ọmọ naa gbe. Wọn ka wọn mọ’bẹ lojiji, wọn mu wọn ṣinkun, wọn si gba ọmọdekunrin naa lọwọ wọn.

Ẹka ti wọn ti n gbọ ẹjọ awọn ajinigbe lawọn maraarun wa bayii nipinlẹ Ogun, nibi ti CP Edward Ajogun paṣẹ pe ki wọn ko wọn lọ. Nibẹ naa ni wọn yoo ti ṣewadii boya awọn ajinigbe yii ṣẹṣẹ bẹrẹ iṣẹ buruku naa ni abi wọn ti wa lẹnu ẹ tipẹ.

Leave a Reply