Eyi laṣiiri to wa nidii miliọnu rẹpẹtẹ ti wọn ṣeeṣi san si akaunti Rafiu oni POS

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

 Asiri bi ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọku-mọku nilẹ yii, EFCC, ṣe ri ọkunrin kan to n ṣowo POS, Aafaa Rafiu Issa Akuji, to n gbe ni agboole Akuji, Abáyàwó, niluu Ilọrin, ti wọn fẹsun kan pe wọn ṣeeṣe san ọgọsan-an  miliọnu (180m), sinu asunwọn ikowosi rẹ, to si n na an yafun-yafun ti tu sita bayii. Ẹni ti Rafiu fi aadọta miliọnu (50,000000) sọwọ si lo ko sọwọ EFCC.

ALAROYE gbọ pe gende-kunrin kan ti wọn ko darukọ rẹ to n ta oogun ni ṣọọbu kẹmisti kan ni oun pẹlu Rafiu dijọ n ṣe wọlé-wọ̀de, oun si lo n ba Rafiu ra gbogbo awọn ọrọ to ko jọ. Ẹni yii kan naa ni Rafiu fi aadọta miliọnu sọwọ si pe ko ba oun gba a jade nileefowopamọ. Ṣugbọn ni kete to gba owo naa tan ni ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati sise owo ilu mọku-mọku EFCC, pe e lori aago, wọn tẹle e de ṣọọbu rẹ, ni wọn ba ni nibo lo ti ri aduro owo yii, ati pe iru iṣẹ wo lo n ṣe. Ohun kan to sọ ni pe ẹni kan to n ṣiṣẹ POS, lo ni owo ọhun. Bi wọn ṣe lọọ fi panpẹ ofin gbe Rafiu niyi, to fi dẹni to n kawọ pọnyin rojọ nipa ibi to ti rowo naa.

Ẹni kan to sun mọ Rafiu to ni ka ma darukọ oun sọ pe ọdun kan gbako ni owo naa lo lakanti rẹ ko too di pe o bẹrẹ si i na owo ọhun.  O tẹsiwaju pe titi di akoko yii, ko si ẹni to yọju pe oun ni oun ni owo ti wọn n sọrọ rẹ yii, ti Rafiu si n fi owo saanu fun gbogbo awọn ọrẹ to sun mọ ọn. O ran awọn eeyan kan ni Umrah, lorile-ede Saudi Arabia, o fun ẹlomiiran ni miliọnu mẹwaa, oni miliọnu meji ati bẹẹ bẹẹ lọ, kọda o ja orule agboole wọn ni ile Akuji, lagbegbe Abáyàwó, to si tun gbogbo ẹ kan.

Ọkan lara mọlẹbi Rafiu to ba ALAROYE sọrọ sọ pe Rafiu ki i ṣe ole, eeyan jẹẹjẹ ni, ati pe ki i ṣe pe o ji owo naa gbe, ki i si i ṣe pe ẹsẹkẹsẹ ti owo naa wọ akanti rẹ lo bẹrẹ si i na an, owo naa pẹ daadaa nibẹ. O fi kun un pe ọrọ naa ti wa ni kootu bayii, ile-ẹjọ ni yoo fi idi rẹ mulẹ bọya ole ni Rafiu ja tabi ki i ṣe ole, o ni idajọ ko si lọwọ ẹnikẹni.

 

Leave a Reply