Eeyan meji ku lasiko rogbodiyan to ṣẹlẹ n’Ikarẹ-Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan meji lo ku, nigba tawọn mi-in tun fara gbọta, lasiko rogbodiyan tuntun to tun ṣẹṣẹ waye niluu Ikarẹ-Akoko, nijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin yii.

ALAROYE gbọ pe aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ni wahala ọhun ti bẹrẹ pẹlu bawọn eeyan agbegbe meji laarin ilu Ikarẹ ni wọn kọjú ija sira wọn, ti wọn si n yinbọn kíkan kíkan.

Yatọ sawọn eeyan to fara gbọta lasiko rogboriyan ọhun, ọ̀pọ̀ ile ati ṣọọbu itaja ni wọn tun dana sun, ninu eyi ti dukia olowo iyebíye ṣegbe si. Ko sẹni to ti i le sọ ohun to ṣokùnfà rogbodiyan to ṣẹṣẹ waye ọhun lasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ.

Ṣugbọn ọkunrin kan to ba wa sọrọ lati ilu Ikarẹ-Akoko jẹ ko ye wa pe awọn ẹsọ alaabo ti wa nikalẹ lati bójú to iṣẹlẹ naa.

Ọkunrin kan to ba akọroyin wa sọrọ, ṣugbọn to ni ka ma darukọ oun sọ pe pipẹ tawọn ẹṣọ alaabo pẹ ki wọn too de si awọn agbegbe ti wọn ti n ba ara wọn fa wahala fẹẹ ba nnkan jẹ diẹ.

O ni ẹbẹ awọn sijọba ipinlẹ Ondo ni lati tete kede ofin konilegbele lawọn agbegbe ọhun, ki ọrọ naa too fẹju kọja bo ṣe yẹ.

Leave a Reply