Nibi ti Ọlaoluwa ti n ṣiṣẹ ninu oko rẹ lawọn agbebọn pa a si l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ko ti i ṣeni to mọ awọn to ṣeku pa baba ẹni aadọta ọdun kan, Ọlaoluwa Toyinbo, bẹẹ ni ko sẹni to le sọ ohun ti ọkunrin naa ṣe tawọn janduku kan fi pa ọkunrin yii nipakupa sinu oko rẹ to wa nitosi Akurẹ, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii.

Nigba ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, n sọrọ lori iṣẹlẹ naa ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ sawọn oniroyin lalẹ ọjọ Aje, Mọnde ọsẹ yii, o ni awọn mẹrin ni  wọn lọọ kọ lu oloogbe ọhun atawọn agbẹ mi-in mọ inu igbo ọba to wa labule Ifẹloduro, Ala, ni nnkan bii aago mẹrin irọlẹ.

Ọdunlami ni foonu to wa lọwọ Ọlaoluwa atawọn yooku rẹ lawọn janduku ọhun kọkọ gba ki wọn too bẹrẹ si i sa ọkunrin naa ladaa ni gbogbo ara, ti wọn si rí i daju pe o ku patapata ki wọn too sinmi ṣiṣa a ladaa.

O fi kun un pe bi awọn ṣe gbọ nipa iṣẹlẹnaa lawọn lọ sibẹ, ṣugbọn awọn janduku ọhun ti sa lọ awọn ẹṣọ alaabo too debẹ.

ALAROYE gbọ pe awọn agbofinro atawọn mọlẹbi oloogbe ọhun ni wọn jọ pawọ-pọ gbe oku Ọlaoluwa kuro lojuko iṣẹlẹ naa, ti wọn si lọọ tọju rẹ si mọṣuari ile-iwosan kan l’Akurẹ.

 

Leave a Reply