Ọmọdekunrin yii ja bọ sinu odo nla nibi to ti n ṣa ike kiri

Faith Adebọla, Eko

Iku ti ti iba paayan, to ba ṣi ni fila, keeyan dupẹ lọwọ Ọlọrun ni o. Ohun to ṣẹlẹ si ọmọdekunrin ọmọọdun mẹjọ yii, Umeh Onyeka, ko yatọ si keeyan bọ iku lọwọ, ki tọhun si raaye jajabọ, niṣe lọmọ naa re jabọ sinu omi ọgọdọ dudu kan, omi adagun pẹlu oriṣiiriṣii idọti ati ẹgbin inu ẹ, omi naa si mu un patapata ti ko fi sẹni to ri ori ẹ nita rara, amọ awọn panapana tete gbọ nipa iṣẹlẹ naa, wọn si ṣe bẹbẹ titi ti wọn fi ri i fa yọ laaye.

Gẹgẹ bii alaye ti Ọga agba ileeṣẹ panapana ipinlẹ Eko, Abilekọ Margaret Adeṣẹyẹ, ṣe ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’Alaroye lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu  latọwọ Alukoro wọn, Ọgbẹni Shakiru Amodu, o ni nnkan bii aago mẹta kọja ogun iṣẹju ni lawọn gba ipe pajawiri kan lori foonu ileeṣẹ panapana to wa niluu Ejigbo nipinlẹ Eko, ti wọn sọ pe kawọn maa sare bọ, ọmọkunrin kan ti re jabọ sinu omi adagun dudu kan, eyi to wa lopin Opopona Pastor Ọjẹdiran, lapa ẹyin aafin Ọba Ejigbo, nipinlẹ Eko.

O ni iwadii fihan pe niṣe lọmọdekunrin naa n ṣa awọn ike omi ofifo, iyẹn ike bottle water, kaakiri pẹlu awọn ẹlẹgbẹ ẹ, tori wọn ni ti wọn ba ṣa kinni naa to ba pọ daadaa, awọn kan maa n waa ra a lọwọ wọn. Ike yii ni wọn n ṣa kiri ti wọn fi de itosi Canal ọhun ti wọn o fura, afi gẹrẹ si ẹsẹ ọmọ yii, to ja bọ sinu omi ẹgbin dudu naa.

Awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti wọn jọ n ṣa ike ọhun kiri ni wọn ki ere mọlẹ, ti wọn sarẹ polongo fawọn eeyan to wa nitosi pe ọkan lara awọn ti jabọ sinu ọgọdọ dudu o, eyi lo mu kawọn alaanu kan sare tẹ ileeṣẹ panapana Ejigbo laago idagiri.

Ṣa, nigba tawọn panapana naa debẹ, pẹlu iriri ati ọgbọn akọṣẹmọṣẹ wọn, gẹgẹ bo ṣe han ninu fidio kan ti wọn fi lede lori iṣẹlẹ ọhun, a ri i ti wọn fi okun funfun kan kọ ọmọ ọhun lapa ninu omi dudu naa, okun ọhun si ni wọn rọra fi fa a jade diẹdiẹ titi to fi yọri sita ki wọn to wọ ọ kuro ninu omi buruku ti iba ti pakute iku rẹ ọhun.

Loju-ẹsẹ ni wọn ti lọọ fun un ni itọju pajawiri, lati mu kara ẹ balẹ, ẹyin ti wọn si ṣetọju ẹ tan ni wọn fa a le awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ wọn to wa l’Ejigbo lọwọ, lẹyin ti wọn ti ṣe akọsilẹ to yẹ, lawọn ọlọpaa da ọmọ naa pada fawọn obi rẹ, gẹgẹ bi Adeṣẹyẹ ṣe wi ninu atẹjade naa.

Ọga agba awọn panapana ọhun ṣekilọ fawọn obi lati maa wa lojufo nigba gbogbo lori ọrọ awọn ọmọ wọn, ki wọn si maa ṣakiyesi irinsi ati ohun ti wọn n ṣe, tori ewu le wa kaakiri awọn ibi tawọn ogo wẹẹrẹ naa n lọ laimọ.

CAPTION

 

Leave a Reply