Eyi lawọn ileewe aladaani mẹtalelogun tijọba ti pa nipinlẹ Ọṣun

Florence Babaṣọla, Osogbo

Latari bi wọn ṣe ṣi ileewe aladaani lai gba aṣẹ lọdọ ijọba, ati bi ọpọlọpọ awọn ileewe naa ṣe wa layiika ti ko bojumu, ijọba ipinlẹ Ọṣun ti paṣẹ pe kawọn ileewe aladaani mẹtalelogun wa ni titi bayii.

Orukọ awọn ileewe ọhun ni Muslim Comprehensive School, Ọbatẹdo, Iwo, Heritage Nursery and Primary School, Kuti, Iwo, Habebulahi Schools, Kuti, Iwo, Divine Success Academy, Hospital Road, Iwo.

Awọn yooku ni Ejire Comprehensive High School, Asalu, Iwo, Omolara Nursery and Primary School, Testing Ground, Iwo ati Delight Nursery and Primary School, Iwo.

Niluu Ileṣa, awọn ileewe aladaani tijọba ti pa ni Brilliant College, Ilesa, Best Brain N/P School, Ilesa, ati Royal Nursery and Primary School, Ileṣa

Niluu Ẹdẹ, Gift and Grace, Ede North, Fola International School, Owode Ẹdẹ,  ati All-Saints Nursery and Primary School, Iregun.

Nijọba ibilẹ Ayedaade, awọn ileewe tijọba ti pa ni God Mercy Nursery and Primary School, Calpphate College, Oke Ọla, Gbọngan ati Sacholar Ville N/P School, lẹyin Rinsayọ filling station, off West Bypass.

Ijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ ko gbẹyin, wọn ti ileewe Al Hikmah Nursery/Primary School, Ido Ọṣun, Catch them Young Secondary School, Ido-Ọṣun, Ọlaoluwa International School, Agunbẹlewo, Ireoluwa Nursery/Primary School, Church Street, Dada Estate, ati Favour of God Secondary School, Ọkinni pa.

Nijọba ibilẹ Ejigbo, awọn ileewe ti wọn ti pa ni ‘A ONE STAR’, Ifẹ-Ọdan, Victorious Children School, Najeemdeen Model Schools, Hephzibah Kiddies ati Arrabany Nursery and Primary School.

Leave a Reply