Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọmọde to fi akaṣu ẹkọ mẹfa ati odidi ori ewurẹ panu, to ni oun ko ti i ṣetan lati jẹun, ba fẹẹ jẹun ni tootọ, afi ko jẹ odidi apẹrẹ ẹkọ tan?
Aṣamọ ọrọ yii lo ṣe rẹ́gí pẹlu gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Ọba (Sẹnetọ) Rashidi Adewọlu Ladọja, to tun jẹ Ọtun Olubadan ilẹ Ibadan lọwọlọwọ, ẹni to ṣadura ọjọọbi ẹ, ni bò-ń-kẹ́lẹ́ ninu ile ẹ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn (25), oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, ṣugbọn ti odidi gomina ipinlẹ kan, ọmọ ileegbimọ aṣofin apapọ meji, ọpọlọpọ ọba ilu atawọn eeyan jankan jankan lawujọ ba a lalejo, ti ọgba nla to wa ninu ile ẹ ko si gba awọn to waa ki i ku amojuba ọdun tuntun rẹ lorilẹ aye.
Ṣaaju l’Ọba Ladọja ti sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu ALAROYE laipẹ yii pe oun ko ni i ṣe ariya kankan fun ayẹyẹ ọjọọbi ọgọrin (80) ọdun oun lorilẹ aye, nitori inu oun ko dun pẹlu bi awọn adari Naijiria ti ṣe ja awọn ọmọ orileede yii kulẹ.
Ṣugbọn bo tilẹ jẹ pe adura lasan ni baba naa rọra ṣe ninu ile ẹ to wa ni Opopona Ondo, ni Bodija, n’Ibadan, sibẹ, yatọ si bi Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, ṣe ba a lalejo lati fi ijokoo yẹ ẹ si nibi akanṣe adura ọhun, igbakeji gomina meji ọtọọtọ lo tun kopa nibi eto ọhun, nitori bi igbakeji gomina lọwọlọwọ nipinlẹ Ọyọ, Amofin Abdul-Raheem Adebayọ Lawal, ṣe kopa waa nibẹ, bẹẹ ni Ẹnjinnia Rauf Ọlaniyan, ti i ṣe igbakeji Gomina Makinde ni saa rẹ akọkọ nipo naa wa nibẹ.
Ija to waye laarin Makinde pẹlu Ọlaniyan lo mu ki awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ yọ igbakeji gomina ọhun nipo lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kejidinlogun (18), oṣu Keje, ọdun 2022, latigba naa lawọn mejeeji si ti di ṣonṣo meji ti ti ki i foju kanra wọn.
Ṣugbọn ọna iyanu nija alagbara to ti wa laarin awọn mejeeji lati bii ọdun mẹta sẹyin gba wa sopin, Ọba Ladọja lo si pari ija naa fun wọn nibi akanṣe adura to fi ṣami ọjọjọbi ọgọrin ọdun lọjọ Wẹsidee to kọja.
Ija yii ni ko jẹ ki gomina ki igbakeji rẹ tẹlẹ yii nigba to n ki gbogbo eeyan lasiko to de sibi eto naa. Bi Ọba Ladọja ṣe ri eyi lo paṣẹ fun awọn mejeeji lati ki ara wọn, nigba naa ni Ẹnjinnia Makinde ati Ẹnjinnia Ọlaniyan dide ki ara wọn, ti wọn si di mọ ara wọn gbagi.
Lẹsẹkẹsẹ lariwo ayọ lo sọ, ti awọn eeyan si bẹrẹ si i kan saara si Ladọja, fun bo ṣe pariija fun gomina ati igbakeji rẹ tẹlẹ naa.
Nigba to n sọrọ nibi eto ọhun, Gomina Makinde fi ẹmi imoore rẹ han si Ọba Ladọja fun ipa to ko ninu bo ṣe wọle ibo gomina. Bẹẹ lo gbadura ẹmi gigun fun agba oṣelu naa lati le de ipo aṣẹ, iyẹn ori itẹ Olubadan ti gbogbo aye ti n foju sọna fun pe yoo tun de nigba ti asiko ba to.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Bi mo ba n sọ itan igbokegbodo mi nidii oṣelu lai darukọ baba (Ladọja) si i, itan naa ko le kun rara, nitori awọn ni wọn gbe igbesẹ to jẹ ko ṣee ṣe fun mi lati wọle idibo gomina lọdun 2019”.
“Awọn aigbọraẹniye kan le wa laarin wa lẹyin ti mo di gomina tan, mo bẹ yin, Baba, ẹ darijìn mi”.
Lẹyin naa lo lo anfaani asiko naa lati fesi si ẹsun ti awọn eeyan fi n kan an nipa bi ijọba rẹ ṣe n ta ilẹ ipinlẹ Ọyọ ṣaa, o ni, “Awọn eeyan n sọ pe niṣe ni mo n ta ilẹ ipinlẹ Ọyọ ṣaa, ọkan tiẹ wa ti mo ka lori ẹrọ ayelujara, o ni bi anfaani ẹ ba wa fun mi, ma a ta papa iṣere Adamasingba, n’Ibadan, ma a tun ta sẹkiteriati ijọba pẹlu.
“Ṣugbọn ohun ti mo fẹ ki awọn eeyan mọ ni pe idagbasoke ni lati ba ilu, bi idagbasoke ba si maa de, ọna kan naa lo maa gba wa”.
Ilana ẹsin mẹtẹẹta ni wọn fi ṣeto akanṣe adura ọhun, nitori bi imaamu agba ilẹ Ibadan, Sheik
Abubakar Abdulganiyy Agbọtọmọkere, ṣe ko awọn Musulumi sodi fun eto ọhun ni Ẹniọwọ (Ọmọwe) Ọlatinwo Fatoki ati Pasitọ Olusọji Adediji lewaju adura nilana ẹsin Kirisitẹni, nigba ti Oloye Ifalere Ọdẹgbemi Adegbọla, to jẹ Araba ati Olu Iṣẹṣe ilẹ Ibadan, wure nilana ẹsin ibilẹ.
Lara awọn to tun ba Ladọja lalejo fun iṣami ojọọbi ẹ ni Aarẹ Musulumi gbogbo ilẹ Yoruba titi de ipinlẹ Kogi ati Delta, Alhaji Dawud Makanjuọla Akinọla, Sẹnetọ Sarafadeen Abiọdun Alli, to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ọyọ nileegbimọ aṣofin apapọ ilẹ yii; Sẹnetọ Abdulfatai Buhari, to n ṣoju ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ; awọn ẹbi atawọn ololufẹ Ọtun Olubadan naa.
Ibrahim Alagunmu, Ilọrin