Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Akwa Ibom, ti tẹ obinrin kan, Imaobong Sampson, to parọ pe wọn ji oun gbe nitori ati le gbowo lọwọ awọn mọlẹbi rẹ.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Waheed Ayilara, lo sọ eleyii di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ nibi ti wọn ti n ṣafihan awọn afurasi tọwọ tẹ loṣu yii niluu Uyo, olu ilu ipinlẹ naa, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹta, ọdun yii. O ni obinrin to wa lati abule Nung Oku, to wa nijọba ibilẹ Ibesikpo Asutan, lo ṣeto ijinigbe ara ẹ.
Miliọnu mẹrin Naira ni wọn lo beere fun gẹgẹ bii owo itusilẹ, ki ọwọ palaba oun atawọn afurasi ti wọn jọ ṣeto ijinigbe naa to segi.
O ni ni kete tọwọ awọn agbofinro tẹ wọn ni wọn tọka si Imaobong gẹgẹ bii ẹni to mu iṣẹ wa, to si ṣeto bi gbogbo nnkan naa yoo ṣe lọ.
“Ni nnkan bii aago mẹwaa aarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni iroyin tẹ wa lọwọ lati ọdọ Enobong Sampson, pe wọn ji ẹgbọn oun obinrin, Imaobong Sampson, gbe, ati pe miliọnu mẹrin Naira lawọn ajinigbe naa lawọn fẹẹ gba.
“Nitori bẹẹ lawọn ikọ to n gbogun ti ijinigbe nileeṣẹ ọlọpaa ṣe bẹrẹ itọpinpin, eyi to ṣokunfa bi wọn ṣe mu awọn ayederu ajinigbe ati ẹni to loun wa nigbekun.
“Ni nnkan bii aago mọkanla alẹ kọja iṣẹju mẹẹẹdogun ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn lọọ fi panpẹ ofin gbe ẹni to ni wọn ji oun gbe, iyẹn Imaobong ati ọrẹkunrin ẹ, Beltus Ebong, nibi ti wọn fara pamọ si labule Mbierebe Obio, ijọba ibilẹ Ibesikpo Asutan, nipinlẹ naa.
“O jẹwọ pe ọrẹkunrin oun, Beltus atawọn mẹta kan loun lẹdi apo pọ pẹlu lati kede pe wọn ti ji oun gbe, lojuna ati le rowo gba lọwọ anti oun to n gbe l’Oke-Okun”.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni awọn afurasi yii, atawọn mi-in ti wọn jọ foju wọn hande lawọn yoo ko lọ siwaju adajọ ni kete tawọn ba ti pari iwadii.