Iku Oloye Bọla Ige ti wọn ni mo lọwọ ninu rẹ, eyi ni b’ọrọ ṣe jẹ-Sunday Igboho

Adewale Adeoye

‘’Irọ buruku ni wọn pa mọ mi. Emi o lọwọ ninu iku Oloye Bọla Ige o, bẹẹ ni Tinubu ko gbe owo fun mi, ko si ran ẹnikẹni si mi ri lati gbowo fun mi ko too di Aarẹ ati nigba to wa nipo Aarẹ bayii. Ẹẹkan naa ni mo ri Tinubu ri laye mi, mi o si tun ti i foju kan an mọ latigba naa.

‘’Kin ni mo fẹẹ lọwọ ninu iku Bọla Ige fun. Ni gbogbo asiko iṣẹlẹ naa, ilu Mọdakẹkẹ ni mo wa ti mo n ba wọn jagun, irọ patapata ni gbogbo ohun ti wọn sọ nipa mi. Ti ko ba si da yin loju, ẹ pe Tayọ Ayinde ti wọn darukọ kẹ ẹ fọrọ wa a lẹnu wo boya ootọ ni emi pẹlu rẹ rira, koda mi o mọ ẹni ti wọn n pe bẹẹ, mi o si ri i soju ri.

ALAROYE, emi ki i ṣe apaayan, mi o paayan ri, wọn ko si mu mi fun ẹsun ipaniyan nibikibi’’.

Wọnyi lawọn ọrọ to n jade lẹnu ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Sunday Majasọla Adeyẹmọ, ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, nigba ti ALAROYE pe e lori aago lalẹ ọjọ Aiku, Sunday, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, lati gbọ tẹnu rẹ lori ọrọ kan to n ja ranyin lori ayelujara pe Aarẹ Bọla Tinubu gbowo fun un nigba kan, ati pe o wa lara awọn to pa Bọla Ige.

Ohun to bi gbogbo ọrọ yii ni itakurọsọ kan to lu sita. Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, lo n ba ẹnikan sọrọ lori foonu, to si fi awọn ẹsun wọnyi kan Sunday Igboho.

Bo tilẹ jẹ pe ilẹ ti ta sọrọ naa, nitori lati ọdun 2021 ni Gani Adams ti sọrọ naa, iyẹn ko too di pe eto idibo ọdun 2023 waye, ṣugbọn laipẹ yii ni awo ọrọ ọhun lu sita pẹlu bi ẹnikan to ni itakurọsọ to waye laarin Aarẹ Ọna Kakanfo ati ọkunrin mi-in to jẹ ara ilu Oyinbo ṣe ju u sita, to si di tọrọ fọnkale lori ayelujara.

Ninu atẹjade kan ti agbẹjọro Sunday Igboho, Ọlatayọ Ogedengbe, fi sita lori ọrọ naa lo ti sọ pe, ‘‘O ṣe pataki pupọ fun mi lati ṣe ipade yii, ki n le fi anfaani naa sọrọ nipa itakurọsọ kan to ti gba ori ayelujara kan bayii.

‘‘Ninu itakurọsọ naa ti Aarẹ Ọna-Kakanfo ilẹ Yoruba, Iba Gani Adams, ṣe jẹ eyi to ba ta ẹrẹ ba orukọ mi.

Oriṣiriṣii nnkan ti ko dara ni wọn sọ nipa mi. O darukọ Aarẹ ilẹ wa, Bọla Ahmed Tinubu atawọn eeyan kọọkan to lorukọ nilẹ Yoruba.

‘‘Ninu ọrọ ti Aarẹ Gani Adams ba ẹnikan sọ lori foonu ọhun lo ti sọ pe mo lọwọ ninu iku Ologbe Bọla Ige (SAN), to jẹ minisita fun eto idajọ lasiko ti wọn pa a nipakupa.

‘‘Mi o ni i salai mẹnu ba a pe ko si ẹri kankan nibikibi ti wọn ti so mi papọ mọ iku to pa Oloye Bọla, afigba ti ọrọ ti ko lẹsẹ nilẹ, ọrọ ibanilorukọ wọnyi jade lati ẹnu Aarẹ Gani Adams si mi.

‘‘Mo fẹẹ fi akoko yii sọ ọ ni gbangba pe mi o mọ ohunkohun nipa bi wọn ṣe pa Bọla Ige tabi bi iku rẹ ṣe waye. Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kejila, ọdun 2001, ni Oloye Bọla Ige ku, ati pẹlu iroyin ti awọn iweeroyin gbe, ọmọkunrin kan ti wọn n pe ni Fryo ni wọn mu nipa iku baba naa.

Lọdun 2001 ta a n sọ yii, ọrọ ogun Ife-ati Modakẹkẹ la n yanju nigba naa. Mo si le ranti daadaa pe ọdun yii kan naa ni wọn ju Aarẹ Gani Adams sẹwọn niluu Eko, nigba ti wọn fẹsun ipaniyan ati dida omi alaafia ilu ru kan an latari ija ẹlẹyamẹya to waye niluu Eko lọdun 2020. Ileeṣẹ Oloogbe Gani Fawehinmi lo duro fun un, ti wọn si gba beeli rẹ ni ile-ẹjọ giga to wa ni Ikoyi, niluu Eko.

‘’Mo pe Gani Adams nija lati bọ si gbangba ko waa fidi awọn ọrọ to sọ wọnyi mulẹ.

‘’O sọ pe ẹnikan to n jẹ Tayọ Ayinde fun mi lowo ni otẹẹli rẹ to wa ni Ikẹja, lorukọ Aṣiwaju Bọla Tinubu, to ti di Aarẹ Naijiria bayii. Mo fẹẹ sọ ọ fun gbogbo aye pe emi ko lọ si otẹẹli kankan niluu Eko lati gbowo lọwọ ẹnikẹni lorukọ Aṣiwaju Bọla Hamed Tinubu latigba to ti di Aarẹ.

‘’Lodi si ohun ti Gani Adams sọ ninu itakurọsọ naa, ko sigba kankan ti ẹnikẹni gbe mi lọ sile-ẹjọ fun ẹsun ipaniyan, bẹẹ ni mi o si paayan ri, eyi to le sọ mi di ero ile-ẹjọ.

‘’Ohun ti itakurọsọ naa tumọ si ni pe Gani Adams ni ikunsinu pẹlu mi. O wa ninu akọsilẹ pe pẹlu gbogbo ọwọ ti mo fun un gẹgẹ bii ọkan ninu awọn oloye niluu Ọyọ, oriṣiiriṣii awọn nnkan ti ko daa to sọ nipa mi latẹyinwa kun ori ayelujara.

‘’Nipari, mi o ba Aarẹ Gani Adams du ipo rẹ.

Njẹ asiko ko ti to fun Aarẹ lati dagunro bayii.

Orileede Yoruba nilo iṣọkan lasiko to lewu gidigidi ta a wa yii, ki i ṣe asiko fun ọtẹ ati ilara.

‘’Mo fi gbogbo awọn ohun ti mo ti sọ yii le ẹyin eeyan ilu lọwọ lati gbe e yẹwo. Bo tilẹ jẹ pe ipinnu mi tẹlẹ ni lati pe e lẹjọ, ṣugbọn awọn eeyan gba mi nimọran lati ri i gẹgẹ bii iti ọgẹdẹ ti ko to ohun aa yọ ada si lasiko ti ilẹ Yoruba wa ninu ewu.

‘’Ẹ ṣeun, mo dupẹ’’.

Oloye Sunday Igboho ti gbogbo eeyan mọ si Igboho Ooṣa.

Nigba ti ALAROYE pe agbẹjọro Sunday Igboho, Ọlatayọ Ogedengbe, sori aago, alaye tọkunrin naa ṣe ni pe awọn ko ṣetan lati gbe Aarẹ lọ sile-ẹjọ lori ọrọ yii gẹgẹ bo ṣe wa ninu atẹjade ọhun. Agbẹjọro naa sọ pe nibi ti nnkan de duro lasiko yii nilẹ Yoruba,  ati bi ogun Fulani ṣe yi wa po, bi Yoruba ṣe maa bọ ninu igbekun yii lo ṣe pataki bayii.

Agbẹjọro Igboho ni ohun to ṣe koko ninu ọrọ naa ni pe Igboho ti fesi lati sọ pe ohun ti Aarẹ Gani Adams sọ ninu fọnran naa ki i ṣe ootọ, ṣugbọn ti ọkunrin naa ba ni awọn ẹri lati fi gbe ọrọ rẹ lẹyin, o le bọ sita lati ṣe bẹẹ.

Nigba ti akọroyin ALAROYE beere lọwọ rẹ boya igbesẹ n lọ lati pe awọn akikanju ọmọ Yoruba mejeeji yii lati yanju ohun to n lọ laarin wọn yii, ohun to sọ ni pe awọn agbaagba Yoruba wa niluu, awọn naa ri, wọn si gbọ ohun to ṣẹlẹ, bi idi pataki ba wa lati ṣe eleyii, wọn maa gbe igbesẹ lori rẹ.

O waa rọ gbogbo ọmọ Yoruba pe ki wọn jẹ ki wọn dawọ ogun duro, ki wọn gba alaafia laaye laarin ara wọn, ka le raaye koju awọn ọta to yi ilẹ Yoruba ka.

ALAROYE fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si Aarẹ Gani Adams lati mọ iha ti ọn kọ sọrọ naa, ṣugbọn wọn ko ti i fesi si atẹjiṣẹ naa titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Leave a Reply