Adewumi Adegoke
Bo tilẹ jẹ pe ojoojumọ ni wọn n ri i laarin awọn ọmọ ẹgbẹ APC, ki i ṣe pe wọn n ri i nikan ni, ọkunrin gomina tẹlẹ naa wa si gbangba lati polongo ibo fun awọn ọmọ ẹgbẹ APC kan, ṣugbọn pẹlu gbogbo ẹ naa, Ayọdele Fayoṣe ti i ṣe gomina Ekiti tẹlẹ yii ni ko si ninu erongba oun lati darapọ mọ ẹgbẹ APC.
Lasiko ti ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels gba a lalejo lori eto wọn kan lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun yii, lo sọ eleyii di mimọ.
Ọkunrin ti wọn tun maa n pe ni Oshoko yii ṣalaye pe oun ko kabaamọ pe oun ṣatilẹyin fun Bọla Tinubu lati di aarẹ Naijiria, boya lasiko yii tabi lọjọ iwaju. O ni idi toun fi ṣe bẹẹ ni lati tẹle ilana pin-in-re la-a-re, leyii to tumọ si pe apa Guusu lo yẹ ki oludije sipo aarẹ ti wa. Fayoṣe ni idi ti oun fi ṣatilẹyin fun Tinubu niyi, oun ko si fi ifẹ ti oun ni si ọkunrin naa pamọ.
O ni oun ki i ṣe ẹni to maa sọrọ kan lasiko yii, to maa di ọdun mi-in, ti yoo si wa nnkan mi-in sọ, Fayoṣe ni oṣelu ti oun n ṣe ti kuro bẹẹ, ohun ti oun ba sọ lonii, bo ba di ọpọlọpọ ọdun sasiko yii, oun ko ni i sọ pe oun ko sọ ọ mọ. Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Ekiti naa ni ko si ninu erongba oun rara lati darapọ mọ ẹgbẹ APC.
Nigba to n sọrọ nipa ẹgbẹ oṣelu rẹ, ọkunrin to ti ṣe gomina ipinlẹ Ekiti lẹẹmeji yii ni ẹgbẹ oṣelu awọn ko mura silẹ lati gba ijọba rara. O ni lati ja kulẹ ni gbogbo imura ti wọn mu lasiko eto idibo to kọja ọhun. O waa rọ ẹgbẹ naa lati ri i pe wọn ṣiṣẹ daadaa, to ba jẹ pe wọn feẹ gba ijọba lọdun 2027. Bakan naa lo ni oun lodi si bi ẹgbẹ naa ko se gbe ijọba wa si apa Guusu, to jẹ pe oludije lati ilẹ Hausa ni wọn tun fa kalẹ.
Fayọṣe gba awọn agbaagba oloṣelu nimọran lati fun okun ṣokoto wọn le, ki wọn si ṣe ohun to tọ ati eyi to yẹ, ki wọn si yee gba araalu bii bọọlu kiri, o ni bi bẹẹ kọ, niṣe ni awọn ọdọ to ti n jade bayii yoo gba wọn ti sẹgbẹẹ kan, ti wọn yoo si gba ipo mọ wọn lọwọ, nitori orileede yii ti kuro ni eyi ti awọn oloṣelu yoo kan maa fi ọwọ yẹpẹrẹ mu awọn eeyan ilu.
O sọrọ nipa iwa akin ati igboya ti awọn ọdọ Naijiria ni bayii, eyi to mu wọn jade lati koju awọn agbalagba pẹlu ipinnu, ti wọn si ja agbara gba lọwọ awọn kan ninu wọn.