Jọkẹ Amọri
Owe tawọn Yoruba maa n pa ni pe ‘a ki i ti kootu bọ ṣọrẹ’, ṣugbọn owe yii ko ṣiṣẹ lọdọ ọkan ninu awọn olorin hiphop to gbajumọ daadaa nni, Habib Okikiọla Ọlalọmi, to kọrin Zah zuh zeh, nitori atimọle ọlọpaa to lọ, ti wọn si tun tibẹ gbe e lọ si kootu ti sọ ọ dọrẹ awọn agbofinro bayii. Niṣe lo n ki wọn ni mẹsan-an mẹwaa, bẹẹ lo si gbe orin kan jade nitori tiwọn. Ninu orin naa lo ti fi han pe oun ko ni i ṣejangbọn mọ, ati pe ẹnikẹni to ba tọ oun bayii, tabi to ba sọrọ oun lẹyin, ọlọpaa loun maa fẹjọ rẹ sun. Bẹẹ lo tun ni lẹyin Ọlọrun, ijọba lo kan o.
Gbara ti wọn tu u silẹ latimọle lẹyin ti wọn gbe e elọ sile-ẹjọ ni ọmọkunrin olorin to saaba maa n pariwo ‘wahala, wahala’ yii gbe awo orin kekere naa jade, nibi to ti ki awọn ọlọpaa daadaa, o ni oun ti dọmọ ijọba, bukaata ijọba apapọ loun bayii.
Bakan naa lo forin naa sọ fun awọn ọta to n wa iṣubu rẹ pe ki wọn jawọ lọrọ oun, o ni oun ki i ṣe ẹlẹwọn, nitori pe oun ko wọṣọ ẹwọn, ati pe ẹnikẹni to ba ti ṣẹ oun bayii, oun yoo fi ẹjọ rẹ sun ọlọpaa ni.
Ninu ọrọ orin naa ni Portable ti kọ ọ bayii pe, ‘’Ọmọ ologo glorious, ọmọ ologo to logo tuntun batyii, Lati irawọ, si ẹyẹ Idì, ẹ waa wo oore-ọfẹ ti ki i doju ti ni. Emi ọmọ Ọlalọmi ti wọn n pe ni Portable.
‘‘Wọn gbe mi lọ si ọgba ẹwọn, mi o gbaṣọ, wọn waa doju sọ mi
Ẹ jawọ lọrọ mi o, mi o ki i ṣe ẹlẹwọn.
Wọn gbe mi lọ sọgba ẹwọn, mi o gbasọ, wọn waa lọọ doju sọ mi, ẹ jawọ lọrọ mi o, mi o ki i ṣe ẹlẹwọn.
Sọrọ mi lẹyin ki n pe ọlọpaa
Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa
Lẹyin Ọlọrun ijọba lo ku
Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa
Emi bukaata ijọba
Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa
Wahala ti pọ ju lọrun mi
Ma a fi ẹjọ ẹ sun ọlọpaa’’.
Bayii ni Portable kọ orin naa, eyi to ti gba ori ayelujara kan, tawọn eeyan si n gbọ ọ daadaa.
Bẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹta, oṣu Kẹrin, ọdun yii, iyẹn lọjọ Aje, ni wọn wọ oṣere naa lọ sile-ẹjọ kan ni ilu Ifọ.
Awon ọlọpaa ni wọn mu-un lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹta, ti wọn sọ ọ satimọle. Latibẹ ni wọn ti gbe e lọ sile-ẹjọ.
Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe o kọ lati da awọn ọlọpaa loun nigba ti wọn pe e. Wọn tun ni o di awọn ọlọpaa lọwọ ninu iṣẹ iwadii wọn pẹlu bi wọn ṣe fẹẹ mu un ti ko gba. Bakan naa ni wọn ni o sakọlu si ọlọpaa kan, to si ṣe e leṣe.
Lara ẹṣun mi-in ti wọn fi kan an ni pe o lu alaamulegbe rẹ.
Ṣugbọn lẹyin ti adajọ kootu ọhun gbọ ẹjọ naa, wọn gba beeli rẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun Naira.
Ẹkọ to kọ latimọle naa lo sọ ọ di ọrẹ awọn ọlọpaa, to si sọ pe ẹnikẹni to ba ti tọ oun bayii, oun maa lọọ fẹjọ rẹ sun ọlọpaa ni.