O ma ṣe o, ọdẹ adugbo pokunso l’Ado-Ekiti, ṣugbọn ọlọpaa ni wọn pa a ni

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Kayeefi nla ni iku ọkunrin ẹni aadọta ọdun (50), kan jẹ fun gbogbo eeyan adugbo Dalimore, niluu Ado-Ekiti, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Ekiti, laaarọ ọjọ ọdun Ajinde, ti i ṣe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹrin, ọdun yii, pẹlu bi wọn ṣe ṣadeede ba oku rẹ nibi to pokunso si labẹ igi mangoro kan to wa laduugbo naa.

Oloogbe yii ti n ṣiṣẹ ọlọdẹ adugbo naa lati bii ọdun mẹta sẹyin, afi bi wọn ṣe ba oku rẹ nibi to ti n rọ dilodilo labẹ igi mangoro, laaarọ kutukutu ọjọ Aiku, Sannde, eyi to da ibẹrubojo silẹ, to si n ṣe awọn eeyan adugbo naa ni haa-hin-in.

Ko sẹni to ti i le sọ ohun to ṣokunfa iku ọkunrin naa titi di akoko ta a fi n ko iroyin yii jọ, bakan naa ni wọn ko ri iwe kankan to ṣee ṣe ki okunrin ọlọdẹ yii kọ silẹ ko too gbẹmi ara ẹ. Ṣugbọn awọn eeyan adugbo naa sọ pe iṣẹlẹ naa waye ni oru ọjọ Satide mọju ọjọ Ajinde ni.

Ẹnikan to n gbe laduugbo naa ṣalaye fun akọroyin wa pe ni deede aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ Satide, lawọn ri oloogbe yii kẹyin lagbegbe naa to n rin kaakiri adugbo, ko si jọ bii pe aburu kankan tabi aisan n ṣe e.

Awọn ẹgbẹ onile (Landlord) adugbo tiṣẹlẹ ọhun ti waye ni iku ọkunrin naa ṣe wọn loju firi, wọn ni iku rẹ mu ifura lọwọ. Awọn ni wọn lọọ fi ọrọ naa to awọn ọlọpaa leti, eyi si lo fa a tawọn agbofinro fi ranṣẹ pe eeyan meji laduugbo naa lati waa sọ ohun ti wọn mọ nipa iku okunrin ọlọdẹ ọhun.

Nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ naa, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe wọn ti ranṣẹ pe awọn lanlọọdu meji laduugbo naa pe ki wọn waa sọ ohun ti wọn ba mọ nipa bi ọkunrin ẹni aadọta ọdun naa ṣe ku, ati iru ọna to gba ku yii.

O tẹsiwaju pe awọn meji ti wọn ranṣẹ pe ọhun ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ bayii lati le ri okodoro iku to pa ọkunrin ọdẹ alẹ naa.

Abutu ni oun ba awọn mọlẹbi oloogbe naa kẹdun lori iku eeyan wọn, o ni pẹlu okun lọrun ni wọn ba oku ọkunrin naa, ṣugbọn ẹsẹ rẹ mejeeji wa nilẹ, eleyii to sọ pe o fihan pe awọn kan ni wọn pa a, ti wọn si waa kẹ oku naa kalẹ sabẹ igi mangoro, ko le baa da bii pe oun lo binu para ẹ.

Agbẹnusọ ọlọpaa yii tun ṣalaye siwaju si i pe bo tilẹ jẹ pe ko si iwe kankan to jẹ akọsilẹ latọwọ oloogbe ọhun, awọn ọlọpaa fura si iku ọkunrin ọlọdẹ adugbo ọhun.

O fi kun un pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ yii.

 

Leave a Reply