Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Gomina ipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, ti ṣeleri fun awọn araalu pe kesekese ni awọn àrà tijọba rẹ ti da laarin ọgọrun-un ọjọ sẹyin lori aleefa, kasakasa n bọ lọna.
Ninu ọrọ ti gomina sọ ninu ipade oniroyin to fi ṣami ọgọrun-un ọjọ to dori aleefa, ni Adeleke ti ṣalaye pe eto ọrọ-aje ipinlẹ Ọṣun ti yatọ lẹnu iwọnba igba toun de, bẹẹ ni igbaye-gbadun awọn araalu ni ohun ti oun kọkọ mu gbọ.
Lai fi ti ẹgbẹ oṣelu ṣe, Adeleke ni ijọba oun ti dawọ le gbogbo awọn akanṣe iṣẹ ti awọn ijọba to ti kọja lọ pa ti, bẹẹ ni koriya wa fun awọn oṣiṣẹ ti wọn ko fimẹlẹ ṣiṣẹ.
Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, gbogbo wọọdu ojilelọọọdunrun o din mẹjọ to wa nipinlẹ Ọṣun nijọba ti gbẹ kanga-dẹrọ kọọkan si, bẹẹ ni oju ọna onikilomita lọna ogun nijọba da ọda si kaakiri.
O ni miliọnu lọna okoolelẹẹdẹgbẹta o din meji Naira nijọba fun awọn agbegbe kan fun iṣẹ idagbasoke, bẹẹ ni wọn ṣiṣẹ abẹ ọfẹ fun ẹgbẹrun meji eeyan ni ẹkun idibo kọọkan, to tumọ si pe eeyan ẹgbẹrun lọna mejidinlogun ni wọn janfaani iṣẹ-abẹ naa.
Gomina Adeleke sọ siwaju pe ijọba oun ti bẹrẹ si i san owo-oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn oṣiṣẹ-fẹyinti tijọba ana jẹ wọn, eyi ti si jẹ koriya fun awọn oṣiṣẹ.
Bakan naa ni ipinlẹ Ọṣun ti wa lori ikanni ayelujara bayii kaakiri fun gbogbo agbaye lati mọ ohun to ba n lọ nibẹ loorekoore. O ni ẹgbẹrun mẹta eeyan nijọba forukọ wọn silẹ lọfẹẹ fun eto ilera adojutofo.
Gomina Adeleke waa fi da awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun loju pe ọpọlọpọ awọn nnkan meremere lawọn ti la kalẹ fun wọn, o waa rọ wọn lati dibo wọn fun gbogbo awọn oludije funpo ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọṣun labẹ ẹgbẹ PDP, lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ọdun yii.