Lẹyin ọjọ marun-un ti wọn ti n wa Elijah ni wọn ba a nibi to pokunso si

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kayeefi patapata lọrọ iku ọmọkunrin kan, Elijah Akinrinlọla, ṣi n jẹ fawọn ẹbi rẹ pẹlu bi wọn ṣe ba a lori igi to pokunso si lẹyin ọjọ bii marun-un ti wọn ti n wa niluu Bágbè, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ondo, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ karun-un, oṣu Kẹta yii.

ALAROYE gbọ pe ẹru nla ni iṣẹlẹ iku ọmọ ọdun mẹtadinlogun naa ti da sọkan awọn ẹbi rẹ pẹlu awọn eeyan ilu ọhun latari bi ohun to ṣokunfa igbesẹ to gbe naa ṣe sokunkun si wọn ni gbogbo asiko ta a n ko iroyin yii jọ lọwọ.

Elijah ni wọn lo n gbe lọdọ baba rẹ nile wọn to wa lagbegbe College, niluu Bágbè. Lojiji lo deedee kuro nile, ti ko si sẹni to le sọ pato ibi to gba lọ.

Ninu alaye ti araadugbo kan to porukọ ara rẹ ni Helen, ṣe fun wa, o ni awọn eeyan ko fi bẹẹ ja ọrọ ọhun kunra nigba ti wọn ko ri Elijah ko wa sile waa sun lọjọ àkọ́kọ́, nitori ọpọ igba lo ti maa n lọ bẹẹ ti ki i wale.

Ṣugbọn nigba ti wọn ko tun ri i ko pada wale waa sun lọjọ keji ni wọn bẹrẹ si i wa a, o ni lẹyin ọjọ karun-un ti awọn ti n wa lawọn eeyan kan too ṣẹṣẹ ri i nibi to pokunso si nitosi adugbo ti oun ati baba rẹ n gbe.

Ẹlomi-in to porukọ ara rẹ ni Samuel ṣalaye fun akọroyin ALAROYE ni ẹnikan to n wa igbin kiri inu igbo lalẹ ọjọ Aiku, Sannde, lo ṣalabaapade oku rẹ to n rọ dirodiro lori igi to pokunso si.

O ni ohun ti oun gbọ nipa rẹ ni pe iṣẹ kafinnta ni ọmọkunrin naa n kọ nigba aye rẹ, ṣugbọn oun ko le sọ boya o pari tabi ko pari iṣẹ kikọ ọhun ko too gbẹmi ara rẹ.

Awọn ẹbi oloogbe ọhun la gbọ pe wọn ti fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro leti, wọn si ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii lori rẹ.

 

Leave a Reply