Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Loootọ ni owe Yoruba maa n sọ pe akọ igi ko gbọdọ soje, bẹẹ lọrọ si ri lọdọ Dokita Rahaman Adedoyin, iyẹn lẹyin ti Onidaajọ Adepele Ojo ka idajọ rẹ tan, to ni oun paṣẹ ki wọn lọọ yẹgi fun ọkunrin to ni ileewe giga Fasiti Oduduwa yii titi ti ẹmi yoo fi bọ lera rẹ. Ṣugbọn ko si ẹni to maa gbọ ọjọ iku rẹ ti ko ni i bara jẹ. Niṣe ni oju ọkunrin yii yipada, beeyan ba si wo irisi rẹ nile-ẹjọ lọjọ Iṣẹgun yii, tọhun yoo mọ pe oogun to n jade lara ọkunrin naa gbona janjan bii omi gbigbona ni.
Bi adajọ ti pari ọrọ rẹ ni Adedoyin nawọ soke, o loun ni ohun ti oun fẹẹ sọ. Ṣugbọn Adajọ Ojo ṣẹwọ si lọọya Adedoyin, o beere lọwọ ẹ pe ki lọkunrin naa fẹẹ sọ. N ni agbẹjọro rẹ ba ni ki adajọ jọwọ jare, ko gba onibaara oun laaye lati sọrọ, nigba ti wọn gbe gbohun gbohun si i lẹnu. Taanu taanu lọkunrin naa fi sọ pe, ‘Ọlọrun ri mi o, O mọ pe mi o paayan, mi o si ran ẹnikẹni lati paayan… Ọrọ yii lo n sọ lọwọ ti Adajọ agba fi da a mọ ọn lẹnu, lo ba ni , ‘oni ki i ṣe ọjọ ọrọ o, o ni ọrọ lẹyin idajọ niyẹn, ko si le tẹwọn lẹyin ti idajọ ti waye, wọn ni to ba de ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun, ko maa lọọ sọ gbogbo ohun to ba ni lọkan to fẹẹ sọ.
Eyi to ṣẹ ọpọ eeyan laaanu ninu ọrọ naa ni ti ọkan ninu awọn ọmọọṣẹ Adedoyin ti wọn jọ dajọ iku fun wọn. Niṣe ni ọmọkunrin naa wolẹ lẹṣẹ ọga rẹ, to si bẹrẹ si i sunkun kikoro.