Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Iyalẹnu nla lo jẹ fawọn eeyan ipinlẹ Ondo nigba ti wọn ri orukọ Olumide Ogunjẹ ti oludije sipo gomina labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ondo, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, fi silẹ gẹgẹ bii igbakeji rẹ ninu eto idibo to n bọ lọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun ta a wa yii.
Orukọ aṣofin to n ṣoju awọn eeyan ijọba ibilẹ Irele ati Okitipupa l’Abuja, Ọnarebu Gboluga Ikengboju, ati Abilekọ Bankẹ Sutton to ti figba jẹ amugbalẹgbẹẹ gomina ana nipinlẹ Ondo, Dokita Olusẹgun Mimiko, la gbọ pe oludije ọhun kọkọ fi silẹ ni olu ile ẹgbẹ wọn lọsẹ to kọja.
Orukọ Ọnarebu Gboluga gan-an lawọn eeyan n reti pe ki wọn kede gẹgẹ bii igbakeji rẹ, koda awọn eeyan kan ti n ki ọmọ ile-igbimọ aṣofin ọhun ku oriire lori itakun ayelujara ki ajọ eleto idibo lorilẹ-ede yii too ṣẹṣẹ forukọ mi-in to yatọ sita laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ yii.
Ilu Irele, ni ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Ondo ni Ogunjẹ ti wa, yatọ si iṣẹ agbẹjọro to yan laayọ, o tun jẹ ọkan pataki ninu awọn amugbalẹgbẹẹ Ọnarebu Gboluga.
Eyi lorukọ awọn oludije ti ajọ eleto idibo fi sita
Ẹgbẹ osẹlu Oludije Igbakeji
- A Rotimi Adelẹyẹ Akindẹjoye Adeyẹmi Bibiresanmi2
- AA Joshua Oluwafẹmi Adewọle Ogunlẹyẹ Agboọla Williams
3. AAC Adelẹyẹ Adekunle Peter Samuel Tọpẹ Ọmọtọsọ
- ADC Adelẹgan Adedapọ Oluwaṣeyi Akinfọtirẹ TemitọpẹOluṣeyi
- ADP Martins Kunle Ọlatẹru-Ọlagbẹgi Balogun Oluwagbenga Victor
- APC Oluwarotimi Ọdunayọ Akeredolu Lucky Orimisan Aiyedatiwa
- APGA Olowolọba Dele Babalọla Aderẹmi
- APM Aminu Akeem Ọlanrewaju Ọmọyẹni Taiwo Ṣeyi
- APP Adesanya Ọlaoluwa Akinrinlọla Adewale Stephen
- LP Okunade Taiwo Ibitoye Adebọwale
11.NNPP Ọjajuni Joseph Ẹniọla Aroge Bayọde Sunday
12. NRM Funmilayọ Jẹnyọ Ataunoko Mafimiṣẹbi Adetutu
13. PDP Eyitayọ Ọlayinka Jẹgẹdẹ Olumide Ogunjẹ
14. PRP Babatunde Francis Alli Ọladele Paul Oluwaṣẹsan
15. SDP Fasua Peter Oyelẹyẹ Ajayi Rachael Olufunmilayọ
16. YPP Ọjọn Dọtun Hajarat Dupẹ Usman
17. ZLP Benjamin Jairus Ọlarotimi Ẹshọ Emmanuel Olusẹgun.
Ọjọ kejidinlogun, osu kẹjọ, ọdun yii, ni ajọ eleto idibo fun gbogbo awọn ẹgbẹ osẹlu wọnyi da lati fi ṣe pasipaarọ eyikeyii ninu awọn oludije wọn.