Bo tilẹ jẹ pe ireti ọpọ ọmọ Yoruba ni pe labẹ bo ṣe wu ko ri, ajijagbara ọmọ Yoruba nni, Oloye Sunday Adeyẹmọ ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho, yoo jade latimọle ọlọpaa to wa ni orileede Olominira Benin, ṣugbọn ọrọ ko ri bẹẹ nigba ti awọn adajọ orileede naa gbe ipinnu wọn kalẹ, ti wọn si sọ pe ọsẹ mẹta ni yoo tun fi wa laahamọ kawọn too tẹsiwaju lori ẹjọ rẹ.
Ninu idajọ ti wọn ṣe lọjọ naa ni wọn ti pa ọpọ ninu ẹsun ti ijọba Naijiria fi kan an rẹ. Lara rẹ ni awọn ohun ija oloro bii ibọn atawọn nnkan mi-in ti wọn ni awọn ba nile rẹ. Nitori pe ijọba ko le fidi ọrọ naa mulẹ, wọn da Igboho lare lori eleyii. Bakan naa ni ẹsun pe o fẹẹ dalu ru. Awọn agbẹjọro rẹ sọ pe ko si ẹri kankan lati fi gbe eleyii naa lẹsẹ nitori pe wọọrọwọ ni gbogbo awọn iwọde to n ṣe, arikẹ ariyọ lawọn eeyan si n ṣe fun un ni gbogbo awọn ibi to de. Bẹẹ ni wọn fẹsun kan an pe o n da iṣọkan Naijiria ru. Ṣugbọn gbogbo eleyii ni wọn ni ko si ẹri to to lati fidi rẹ mulẹ.
Ṣugbọn ẹsun mi-in ti wọn fi kan an, ti ijọba ilẹ Benin si n reti pe yoo jẹjọ le lori ni pe o wọ ilẹ Benin lọna ti ko tọ, o si tun lẹdi apo pọ mọ awọn aṣọbode ilẹ naa lati ṣe aparutu. Ẹsun kẹta ni pe o fẹẹ waa da omi alaafia ilu naa ru nipa ipolongo Yoruba Nation nibẹ.
Awọn ẹsun mẹtẹẹta yii ni ireti wa pe awọn agbẹjọro rẹ yoo maa ba awọn adajọ ta kangban le lori ni oṣẹ mẹta si asiko ta a wa yii ti igbẹjọ rẹ yoo tun waye.