Ileeṣẹ ologun oju ofurufu ti gbe orukọ eeyan meje ti wọn ku ninu ijamba baaluu agbera-paa to gbina lọjọ Aiku, Sannde, jade.
Ninu ọrọ ti agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun oju ofurufu, Air Vice Marshal Ibikunle Daramọla, fi sita lo ti sọ pe eeyan meje lo ku ninu iṣẹlẹ ọhun.
Awọn eeyan ti wọn ku sinu baaluu ọhun ni Haruna Gadzama, ẹni to wa a; Henry Piyo, awakọ baaluu loun naa ati Micheal Okpara, Bassey Etim.
Awọn yooku ni Ọlasunkanmi Ọlawunmi; Ugochukwu Oluka ati Adewale Johnson.
Minna, nipinlẹ Niger, ni wọn sọ pe baaluu ọhun ti gbera lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, to kọri si Abuja ki ẹnjinni rẹ too daṣẹ silẹ ni nnkan bii aago mọkanla ku iṣẹju mọkanlelogun laaarọ yii.
Nibi ti awakọ baluu ọhun ti nọmba ẹ jẹ NAF201 B350, ti n gbiyanju lati balẹ si Abuja ni kete to ti ri i pe ẹnjinni ọkọ ofurufu ọhun ti daṣẹ silẹ ni baluu ọhun gbina mọ ọn lọwọ.
Minisita fun ọkọ ofurufu, Hadi Sirika, kọ ọ sori ikanni abẹyẹfo ẹ pe, “Ọkọ agbera-paa tawọn ologun ti orukọ ẹ n jẹ King Air 350 ti ni ijamba niluu Abuja lasiko ti awakọ ẹ n gbiyanju lati wa a gunlẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe. Minna, nipinlẹ Niger, ni wọn sọ pe o ti gbera. Ohun ti a si gbọ ni pe ijamba ọhun le pupọ, ṣugb̀ọn mo fẹẹ rọ wa ki a ni suuru titi digba ti abajade iwadii yoo waye.