Eyi ni bawọn arinrin-ajo mẹrin ṣe ku sinu ijamba ọkọ l’Ondo

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan mẹrin ni wọn ku iku airotẹlẹ nigba tawọn ẹlomiiran tun fara pa ninu ijamba ọkọ kan to waye loju ọna marosẹ Akurẹ siluu Ondo, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ lati ẹnu oṣiṣẹ ajọ ojupopo kan pe ijamba yii lo waye ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ lagbegbe kan ti wọn n pe ni Ọ̀pa, n’ijọba ibilẹ Guusu Akurẹ.

O ni ohun to ṣokunfa ijamba ọhun ni bi ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan ti nọmba rẹ jẹ RSH 196 AX pẹlu ọkọ Almera alawọ eweko mi-in to n bọ lati ọna Ondo ṣe fori sọ ara wọn.

Eeyan mọkanla lo ni wọn wa ninu awọn ọkọ mejeeji, obinrin marun-un, ọkunrin mẹrin, atawọn ọmọdékùnrin meji.

O ni loju-ẹsẹ ni mẹta ninu awọn obinrin naa pẹlu agba ọkunrin kan ti ku, ti awọn ero ọkọ ọhun yooku fara pa yannayanna.

Ileewosan ijọba to wa l’Akurẹ la gbọ pe wọn ko awọn to fara pa lọ fun itọju, nigba ti oku awọn to padanu ẹmi wọn pẹlu ṣi wa ni ọsibitu yii kan naa titi tawọn ẹbi wọn yoo fi yọju.

Oṣiṣẹ ẹsọ oju popo ọhun ni pupọ ẹru tawọn ba ninu ọkọ mejeeji lawọn ti ko fawọn ọlọpaa tesan ‘B Difisan’, to wa l’Oke-Aro, l’Akurẹ.

Leave a Reply