Gbenga Amos, Abẹokuta
Titi di ba a ṣe n sọ yii, inu ibẹrubojo lawọn olugbe agbegbe Oluwo si Adigbẹ, Mango ati Ita-Baalẹ wa, ọkan wọn o si lelẹ rara latari ija ajaku akata to n lọ laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun lagbegbe naa. Inu ija naa ni wọn ti pa ọkan lara wọn lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, to kọja, Tommy lorukọ inagijẹ tawọn eeyan mọ oloogbe naa si.
Ba a ṣe gbọ, awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ‘Ẹyẹ’ ati ‘Aiye’ ni wọn jọ tẹsẹ bọ ṣokoto ija, ti kaluku wọn mura ati gbẹsan lara ẹni keji, ti wọn si n dọdẹ ẹmi ara wọn pẹlu awọn nnkan ija oloro ti wọn ko dani.
Ibudokọ Panṣẹkẹ ti wọn ni oloogbe naa sa gba nigba ti wọn n le e ni wọn ka a mọ, wọn fi aake ati ada ṣa a balẹ, wọn si pa a nipa ika.
A gbọ pe ọkan ninu awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun ni Tommy ti wọn pa yii, wọn lọmọ ẹgbẹ ‘Ẹiyẹ’ ni, o ti pẹ ti wọn ti n dọdẹ rẹ latari bi wọn ṣe loun lo wa lẹyin iku awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun keji to waye sẹyin.
Latigba tiṣẹlẹ yii ti waye, paroparo ni gbogbo adugbo Oluwo si Adigbẹ da, niṣe lawọn eeyan tilẹkun mọri pinpin, ọpọ awọn ọlọja ati awọn to n ṣiṣẹ ọwọ ni ko le ṣi ṣọọbu ọja tabi lọ sidii okoowo ati iṣẹ aje wọn, bẹẹ agbegbe yii lawọn akẹkọọ ileewe Poli Moshood Abiọla, to wa l’Ojere, l’Abẹokuta, pọ si. Ọgọọrọ awọn oṣiṣẹ ijọba atawọn olukọ lo n gbe lagbegbe ọhun.
Wọn niṣe lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ti Tommy jẹ ọkan ninu wọn n leri pe awọn maa gbẹsan iku rẹ, ti wọn si n lepa ara wọn kitakita kiri adugbo ọhun.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti gbe igbesẹ lori iṣẹlẹ yii. Ninu atẹjade kan latọwọ Alukoro wọn, DSP Abimbọla Oyeyẹmi, lọjọ Ẹti, Furaidee, o ni gende mejidinlogun lawọn ti mu satimọle lara awọn adaluru ọhun, awọn o si ti i dawọ duro.
Bi ọkọ awọn ọlọpaa ṣe n lọ to n bọ, lẹnu patiroolu wọn, bẹẹ lawọn ọlọpaa kogberegbe atawọn ọtẹlẹmuyẹ ti fọn sagbegbe naa, lati wadii, ki wọn le fi pampẹ ofin mu awọn ọmọ alaigbọran adaluru ọhun, ki wọn si pese aabo faraalu.
Oyeyẹmi to gbẹnu sọ fun Kọmiṣanna ọlọpaa Ogun, CP Lanre Bankọle, fi awọn araalu lọkan balẹ, o lawọn agbofinro ti wa lojufo lati pese aabo fun wọn, ati pe iroyin ẹlẹjẹ ati idẹruba ni awọn eeyan kan n gbe sori ẹrọ ayelujara nipa iṣẹlẹ naa, o ni abumọ lo pọ ninu ọrọ wọn.