Eyi ni bi awọn oludije ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe wọle ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn ni ipinlẹ Ọyọ 

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, iyẹn, Ọyọ State Independent Electoral Commission (OYSIEC), kede esi idibo ijọba ibilẹ to waye kaakiri ipinlẹ naa lọjọ Abamẹta, Satide.

Ẹgbẹ oṣelu Alaburada, iyẹn People’s Democratic Party, ta a mọ si PDP, lo jawe olubori ninu gbogbo ijọba ibilẹ mẹtẹẹtalelọgbọn (33) to wa ni ipinlẹ naa.

Amọ ṣa, ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, iyẹn All Progressives Congress (APC), ti fi aidunnu wọn han si esi idibo naa, wọn ni kikida aparutu ati magomago lo kun inu eto naa bamubamu.

Nigba to n kede esi idibo ọhun, alaga ajọ OYSIEC, Aarẹ Isiaka Ọlagunju, ṣapejuwe eto naa gẹgẹ bii eyi ti wọn ṣe pẹlu akoyawọ, ti wọn ko si fi ṣegbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kankan.

Ọlagunju, to tun jẹ amofin agba (SAN), nilẹ yii, waa gboṣuba fawọn ọlọpaa, ajọ eleto aabo ara ẹni laabo ilu, iyẹn Nigeria Security and Civil Defense Corpse (NSCDC), atawọn ajọ eleto aabo yooku ti wọn pese aabo ti eto idibo ọhun fi kẹsẹ jari.

Ẹ̀wẹ̀, nigba ti awọn ẹgbẹ oṣelu alatako n fapa janu, ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kira wọn kuu oriire lori esi idibo naa, ṣe ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn kede gẹgẹ bii ẹgbẹ to wọle idibo gbogbo ipo alaga kansu ipinlẹ yii naa lo n ṣejọba ipinlẹ yii lọwọ.

Ninu atẹjade ti Ọmọọba Dọtun Oyelade ti i ṣe kọmiṣanna feto iroyin ninu ijọba Gomina Ṣeyi Makinde fi ṣọwọ sawọn oniroyin, o ni, “Ohun ta a ti reti pe o maa ṣẹlẹ naa lo ṣẹlẹ yii. A ti mọ pe ẹgbẹ oṣelu PDP naa lo maa wọle, nitori aṣeyọri Gomina Makinde ti jẹ ki awọn ara ipinlẹ yii nifẹẹ si ẹgbẹ oṣelu PDP daadaa”.

Amọ ṣaa, awọn aiṣedede kan ko ṣai waye ninu eto idibo naa.

Gẹgẹ bii apẹẹrẹ, awọn oniroyin ilu Ṣaki atawọn ara ilu naa ti akọroyin wa ba sọrọ fidi ẹ mulẹ pe idibo ko waye lawọn ijọba ibilẹ bii Ila-Oorun Ṣaki, Iwọ-Oorun Ṣaki ati Oorelope, bẹẹ, ajọ eleto idibo kede esi idibo nijọba ibilẹ mẹtẹẹta.

Ninu fidio kan to tẹ akọroyin wa lọwọ lawọn araalu ti n fẹhonu han, ti wọn n sọ fawọn ọlọpaa pe, “ẹ tete ba awọn oṣiṣẹ ajọ OYSIEC sọrọ pe ki wọn gbe awọn ohun eelo idibo wa kiakia, ka le dibo, bi bẹẹ kọ, ẹ jẹ ko wa ninu akọsilẹ yin pe idibo kankan ko waye lọdọ tiwa nibi o, ko waa ni i daa ka maa deede gbọ ikede iranu kan, pe ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọle idibo lọdọ tiwa nibi o”.

Oludibo kan to jẹ ọmọ bibi ijọba ibilẹ Ila-Oorun Guusu Ibadan, ṣugbọn ti ko fẹ ka
darukọ oun ṣalaye fakọroyin wa pe, “ajọ OYSIEC lo pari iṣẹ yẹn fun ẹgbẹ oṣelu PDP. Gbogbo ibi ti wọn mọ pe ẹgbẹ PDP ti lẹsẹ nilẹ daadaa ni wọn ko nnkan eelo idibo pupọ lọ, ṣugbọn lawọn ibi ti wọn ba ti ri i pe ẹgbẹ APC ti lẹnu daadaa, nnkan eelo idibo kekere ni wọn ko lọ sibẹ, tabi ki wọn ma tiẹ jẹ ki idibo kankan waye nibẹ rara”.

Leave a Reply