Eyi ni bi mo ṣe sa kuro lakata awọn ajinigbe to mu mi-Ademọla 

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ọkunrin ẹni ọdun mejidinlaaadọta kan, Ọgbẹni Ademọla Adeẹkọ, ti ori ṣẹṣẹ ko yọ lakata awọn ajinigbe ti royin ohun ti oju rẹ ri ati bi ori ṣe ko o yọ lakata wọn.

Ọkunrin yii jẹ agbaṣẹṣe iṣẹ igi lila, o tun n ta aṣọ, ilu Akurẹ, nipinlẹ Ondo, lo fi ṣe ibujoko. Ayika ileeṣẹ to ti n lagi yii lawọn ajinigbe ti ji i ni Aisẹgba-Ekiti, nijọba ibilẹ Gbọnyin, nipinlẹ Ekiti, lọjọ kẹjọ, ọṣu Kẹfa, ọdun 2022.

Ọkunrin yii ni awọn agbebọn ti ko din ni meje ji gbe pẹlu kọngila kan to jẹ Hausa, to maa waa n ra igi lọwọ awọn to n ṣiṣẹ igi ni agbegbe naa.

Nigba to n sọ iriri rẹ fun awọn akọroyin ni Ado-Ekiti, o ṣalaye pe lọjọ ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ gan-an, oun wa ni agbegbe ileeṣẹ lagilagi naa ni Aisẹgba-Ekiti, nibi ti oun ti n ba eto kara-kata oun lọ.

O ni lojiji loun gbọ iro ibọn leralera ni agbegbe ileeṣẹ naa, ti gbogbo eeyan si n sa kijokijo, ti oun si duro lati mọ ibi ti iro ibọn naa ti n dun.

O ṣalaye pe o ti to bii ọdun marun-un ti oun ti n ṣe kara-kata ni agbegbe naa ko too di ọjọ ti wọn ji oun gbe lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni deede aago marun-un aabọ irọlẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Sadeede ni mo n gbọ iro ibọn to n dun lakọkọ nirọlẹ ọjọ naa, ti awọn eeyan si n sa wọ inu igbo lati sa asala fun ẹmi wọn. Eyi lo mu ki emi naa sa gba inu igbo, ṣugbọn o ṣe ni laaanu pe agbegbe inu igbo ti mo sa gba ni awọn agbfinro yii wa gan-an.

“Ṣinkun ni wọn di ọwọ mi mu, ti wọn si sọ fun mi pe emi gan-an ni awọn wa wa si agbegbe naa, lọgan ti wọn mu mi tan ni awọn ajinigbe wọnyi bẹrẹ si i jade ninu igbo, nibi ti wọn ti fara pamọ si, ti wọn si n mu mi lọ si ibi kan ti n ko mọ ri.

“Bi a ṣe n lọ ninu igbo naa ni mo boju wẹyin, mo ri ọkunrin Hausa kan ti mo mọ ni agbegbe naa to maa n ṣe owo igi, wọn n fa a bọ nibi ti mo wa, ṣugbọn lẹyin iṣẹju bii mẹwaa ni wọn yinbọn pa ọkunrin Hausa yii.

‘‘Lẹyin wakati diẹ, mo ba ọkan lara awọn ajinigbe yii sọrọ, mo beere ohun to fa a ti wọn fi yinbọn mọ ọkunrin Hausa naa, o si daun pe nitori pe o sọ fawọn pe oun ko le rin ninu igbo, ati pe oun ko lowo ti oun yoo san fun awọn ni.

“Ẹẹmẹta ni mo gburoo ibọn naa, ẹru si ba mi gidigidi, ṣugbọn wọn sọ fun mi pe ti mo ba ti ṣe gbogbo ohun ti awọn ba sọ fun mi, layọ ati alaafia ni ma a pada darapọ mọ awọn mọlẹbi mi ni ile mi. Wọn fi kun un pe ti mo ba kọ lati gbọ gbogbo ohun ti awọn ba ti sọ fun mi, bi awọn ṣe pa Hausa yii ni awọn yoo pa mi.”

Nigba to n ṣalaye siwaju si i, Adeẹkọ sọ pe awọn ajinigbe ti ko din ni meje, ti mẹrin lara wọn si wa pẹlu ibọn AK-47 lọwọ, kọju oun sinu igbo kan ti oun ko mọ ri, awọn si rin ninu igbo naa fun bii wakati mẹjọ gbako.

O sọ pe ni deede agogo mẹta aarọ ọjọ keji ni awọn duro sinu igbo kan ti Koko wa, ti igbo si gba gbogbo inu oko Koko naa bii pe ẹni to ni oko yii ti fi i silẹ lati bii ọdun mẹwaa.

“Wọn sọ fun mi pe ni ibi ti awọn de yii, awọn ni lati simi. Bi wọn ṣe jokoo ni wọn mu okun nla kan jade ninu apo wọn, ti wọn si so apa ati ẹsẹ mi sẹyin, ti awọn naa si gbe ibọn wọn silẹ, ti wọn si fi mi silẹ sibẹ lati lọọ simi.

Wakati mejidinlaaadọta ni mo fi rin ninu igbo naa lai wọ bata pẹlu ebi ninu.

” Wọn gba gbogbo ẹrọ ilewọ mi, wọn tun gba aṣọ ati gbogbo owo ti wọn ba ni apo mi, nigba to di bii aago mẹta ọsan ọjọ keji, wọn tan ẹrọ ilewọ mi to jẹ GLO, ṣugbọn wọn sọ pe Airtel nikan lo maa n ṣiṣẹ daradara ni agbegbe naa. Bi wọn ṣe n pe awọn mọlẹbi mi ni wọn bẹrẹ si i na mi, ti mo si n kigbe, ti awọn mọlẹbi mi n gbọ bi mo ṣe n japoro, ti mo si n kigbe. Ọgọrun-un miliọnu Naira ni wọn lawọn maa gba gẹgẹ bii owo itusilẹ.

“Mo bẹrẹ si i bẹ wọn, mo si sọ fun wọn pe ki wọn gba miliọnu meji Naira lọwọ mi, ṣugbọn wọn fi aake kọri, ohun to ya mi lẹnu ni pe ọga awọn ajinigbe sọ fun mi pe ki n wo o, meje ni gbogbo awọn, ati pe awọn ti wọn n ta wọn lolobo naa ṣi wa ti wọn yoo gba lati ara owo ti mo ba san.

“Nigba ti Ọlọrun fẹẹ ṣe iṣẹ rẹ, ni ọjọ kẹta ti mo ti wa ni akata wọn, gbogbo awọn ajinigbe mejeeje naa ni wọn sun lọ, ti wọn si gbagbe lati fi okun si ọwọ ati ẹsẹ mi ki oorun too gbe wọn lọ.”

“Bi mo ṣe yọ kẹlẹkẹlẹ ti mo rin kuro lọdọ wọn niyẹn, mo rin ninu igbo naa ni gbogbo oru yii, ṣugbọn nigba ti ile ọjọ keji mọ, mo jade si oju ọna kan, mo tọ ọ diẹ titi ti mo fi ri obinrin kan ati awọn ọmọ rẹ meji ti wọn n lọ soko.

“Mo beere ibi ti mo wa gan-an lọwọ wọn, wọn sọ fun mi pe ipinlẹ Kogi ni mo wa. Mo bẹ wọn pe boya wọn le mu mi jade si oju ọna, wọn gba, wọn si fi ọna han mi, bi a ṣe n lọ ni mo sọ fun wọn pe awọn ajinigbe ni wọn ji mi gbe.

“Bi mo ṣe rin diẹ loju ọna naa ni mo ri ọkunrin ọlọkada kan to gbe mi lọ si agọ ọlọpaa kan ni Ẹkinrinade, nipinlẹ Kogi, mo si ṣe gbogbo alaye ohun ti oju mi ri fun wọn, awọn ọlọpaa yii lo gbe mi pada wa si ipinlẹ Ekiti, lẹyin ti wọn gba ọrọ silẹ lẹnu mi, ti mo si darapọ mọ awọn mọlẹbi mi.”

Bi ọkunrin ti Ọlọrun ko yọ lọwọ awọn ajinigbe naa ṣe pari ọrọ rẹ niyi.

Leave a Reply