Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin oṣu mẹta ti awọn ikọ ọmọ iṣọta ta a mọ si ‘One Million Boys’ pa Moshood Ọladokun (Ẹkugbemi), ọga awọn tọọgi n’Ibadan nipakupa, wọn ti yinbọn pa Abiọla Ẹbìlà, ọga awọn ‘One Million Boys’ nigboro Ibadan.
Awọn ikọ ọmọ ogun Ẹkugbemi ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ ikọ afẹmiṣofo kan ti wọn n pe ni ‘Abẹ-Igi Boys’ la gbọ pe wọn lọọ ka a mọle lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ to kọja, ti wọn si yinbọn pa a gẹgẹ bii ẹsan pipa ti oun naa pa Ẹkugbemi ọga wọn.
Ta o ba gbagbe, ọsan gangan, ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu kẹrin, ọdun 2020 yii, lawọn ọmọ ogun ikọ ‘One Million Boys’ lọọ ka Ẹkugbemi mọle ẹ to n gbe laduugbo Olúǹdé, n’Ibadan, ti wọn si gbẹmi ẹ lẹyin ija alagbara to waye laarin wọn. Niṣe lara awọn to foju kan oku ẹ n ṣẹgiiri nitori bi wọn ṣe fi ada ba oku ẹ jẹ to.
Latigba naa lolori awọn ‘One Million’ ti wọn n pe ni Ẹbila yii ti di ẹni tawọn ọlọpaa n wa, oun naa ko si duro, niṣe lo sa lọ ti ẹnikan ko si gburoo ẹ n’Ibadan ati nibikibi nipinlẹ Ọyọ mọ.
Ṣugbọn ko jọ pe ẹru awọn ọlọpaa lo n ba Ẹbila bii tawọn ẹruuku, iyẹn awọn ọmọ ogun ikọ ‘Abẹ Igi Boys’, o mọ pe gbogbo ọna ni wọn yoo maa wa lati pa oun lati gbẹsan iku ọga wọn, Ẹkugbemi. Nitori bẹẹ, sisa loun naa n sa kiri latigba naa. Nigba to si maa pada de, ko de sinu ile ti gbogbo aye mọ pe o n gbe laduugbo Kudẹti, adugbo Olomi lo lọọ fori pamọ si.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ni nnkan bii aago meji ọsan ọjọ Sannde yii lawọn ẹruuku ka a mọ ibi to fara pamọ si ọhun. Wọn ko si ba oun naa laabọ, oun paapaa pitu meje tọdẹ akọni n pa nigbo fun wọn. Ṣugbọn lẹyin iṣẹju bii meloo kan ti wọn ti jọ n dana ibọn funra wọn ya, ọga awọn ‘One Million Boys’ yii ṣubu loju ija, akọni kile aye pe o digbooṣe.
Iroyin mi-in ta a tun gbọ ni pe awọn agbofinro ni wọn yibọn pa ọga awọn tọọgi to n da omi alaafia igboro Ibadan ru naa.
Wọn ni Ẹbila atawọn ọmọ ẹyin ẹ bii mẹẹẹdogun ji obinrin kan gbe pamọ, ti wọn si ni ki awọn mọlẹbi rẹ lọọ wa miliọnu kan Naira wa bi wọn ko ba fẹ ki awọn yinbọn pa a. Iroyin yii ni wọn fi to awọn ọlọpaa leti ti ikọ awọn agbofinro ijọba ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Operation Burst fi lọọ ka a mọnu ile ọhun, ti wọn si yinbọn pa a, bo tilẹ jẹ pe awọn yooku rẹ ribi sa lọ.
Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe ninu ija nla, nibi ti ikọ ‘One Million Boys’, eyi ti Ẹbila ko sodi, pẹlu awọn ikọ eleto aabo ipinlẹ Ọyọ ti dana ibọn funra wọn ya lawọn agbofinro ti yinbọn pa olori awọn tọọgi naa.
O ni oun ko ti i ni ẹkunrẹrẹ alaye nipa bi wọn ṣe pa ọga ọmọ iṣọta n’Ibadan yii lọwọ, ṣugbọn oun mọ pe kẹkẹ NAPEP lawọn agbofinro to yinbọn pa a fi gbe oku ẹ kuro loju ija ti wọn yibọn pa a si. Wọn si ti tọju ẹ si yara ti wọn n ṣe oku lọjọ si nileewosan ijọba pinlẹ Ọyọ.
SP Fadeyi sọ pe awọn ọlọpaa ti gbakoso eto aabo agbegbe ibi ti wọn gbẹmi ọga awọn tọọgi naa lati dena ija igboro mi-in to ṣee ṣe ko tun waye nigba tawọn ọmọ ẹ ba n gbiyanju lati gbẹsan.